Rema fún ilé-ìjó̩sìn Christ Embassy ní milionu márùnléló̩gó̩rùn ún
Mary Fágbohùn
Olorin Naijiria, Irawo agbaye, Divine Ikubor, ti a mo si Rema, ti fun ile ijosin Christ Embassy ni milionu marunlelogorun un ni ilu Benin, ipinle Edo.
Iroyin jade pe olorin ti a bi ni Edo wa ni ipinle naa fun ajoyo Edo ni eni odun metalelogbon (Edo@33) ti o si korin ni gbongan ti o gba egberun mefa eniyan ni Edo Dome ati ere orin ni papa isere Samuel Ogbemudia ti ijoba ipinle naa pe e si.
Rema, eni to fun olu iya ile ijosin ni Edo, eyi to wa ni adugbo Erediauwa, ni iyana Ekenwa, ni owo so pe o je imoore fun atileyin ti ile ijosin naa se fun ebi oun nigba ti nnkan ko rogbo fun won.
Olorin agbaye naa, eni to se idupe ni ile ijosin naa, seranti ipa ti ile ijosin naa ko ninu ebi oun leyin ti oun padanu baba oun nigba ti oun wa ni omo odun mejo .
Gege bi o se so: “Mi o si nibi lati gboriyin fun tabi fi ogo fun ara mi sugbon lati fi ogo fun Olorun.
“Mo roo pe o se pataki lati pada wa si ile ijosin to gba mi mora, ti won gbadura fun mi, ti won si je ki n wa ni idurosinsin ninu emi.
“Nigba ti mo wa ni omo odun mejo, ti mo padanu baba mi, a sonu, a si dabi eni ikosile.
“Won gba gbogbo nnkan ti a ni, mo ranti igba naa, Olusoaguntan Joy ati Olusoaguntan Thomas, awon Olusoaguntan ile ijosin yii; won si ile itaja fun iya mi, ibe ni won ti rowo ti won fi toju wa.”
“Lakoko, Mo fe jeje milionu lona ogoji naira fun idagbasoke ile ijosin, milionu lona ogun naira fun atejade iwe Rhapsody of Realities ati nitori pe mo wa lati eka awon ipeere ninu ile ijosin yii, mo fe jeje milionu lona ogun o le marun un naira.
“Lati fi kun eyi, ti o ba ni opo ti o wa ninu ile ijosin lonii, mo n jeje milionu lona ogun naira lati ran awon opo ti o wa nibi lonii lowo,” ni o fi kun un.