Orí kó e̩bí mi yo̩ nínú ìjàm̀bá o̩kò̩ – Maraji

Orí kó e̩bí mi yo̩ nínú ìjàm̀bá o̩kò̩ – Maraji

Mary Fágbohùn

Aderinposonu, Maraji ti safihan pe ori ko oun ati ebi re yo ninu ijamba oko.

Ninu fonran kan lori YouTube, o salaye bi ijamba oko naa se waye nigba ti won n bo lati ile ijosin.

Maraji wi pe oko won “yi biribiri fun opo igba ki o to bale.”

Onifonran naa, eni to ti kuro lori ayelujara lati osu kefa 2024, salaye pe ijamba oko naa lo mu ki o yera fun oju gbogbo eniyan.

“Ti e ba ti ni ijamba oko ri, e o mo imolara to wa laarin iku ati iye.

Ohun ti o je ko bami leru gidi ni pe gbogbo wa lo wa ninu oko. Oko mi, emi, ati awon omo mi.

“A n bo lati ile ijosin. O deruba mi, o mu ki n ro pe mo le ku. Ti mo ba ti ku, gbogbo ise ti mo ti se yoo kan lo ni.

“Kin ni koko ise ti eniyan n se laisi isinmi? O wa je ki n moriri aye gidi ati pe ki n se nnkan ti mo feran ju, eyi to je isinmi.

“Ijamba oko naa ya mi lenu. A n wa oko lo nigba ti oko miran gba wa lati egbe ti a si n yi kiri. O dabii fiimu Naijiria, o le ya ni ni were. Oko naa n yi gbirigbiri, leyin naa a ba ara wa ninu koto. Mo wo awon omo mi, ko si nnkan to se won. Mo dupe lowo Olorun to reku danu lori wa.

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here