Mi ò fo̩ aso̩ rí láyé mi – Seun Kuti

Mi ò fo̩ aso̩ rí láyé mi – Seun Kuti

Olorin takasufe Seun Kuti ti so pe baba re to ti di oloogbe, olupinlese orin takasufe, Fela Anikulapo-Kuti, fun ni itoju ti o yato laarin awon ibatan re.

Nigba to n soro lori eto Zero Conditions, Kuti seranti bi won se kee ni omode.

O wi pe, oun je aayo baba oun, o tenumoo pe baba oun je baba daradara si oun, koda bi awon ibatan oun miran ba so pe “baba buruku ni.”

Olorin naa gboya pe nitori ike ni oun ni lati omode, oun ko fo aso ri laye oun.

“Mo je tete baba. Fela Kuti ni aayo mi ni agbaye. Ti e ba beere lowo awon arakunrin mi, won le so pe baba buruku ni sugbon si emi, baba daadaa ni,” gege bi o se salaye.

“E o mo bi won se bami je to nigba ti mo n dagba. Di akoko yi, mi o fo aso ri laye mi. Mi o mo bi won se n fo ohunkohun. Mi o fi yangan.”

O tun safihan pe oun darapo mo egbe orin baba oun, Egypt 80, ni omo odun mejo.

“Mo ti wa pelu egbe orin Fela, Egypt 80 lati igba ti mo ti wa ni omo odun mejo. Nitori naa, nigba ti Fela ku, awon ebi mi ni ki n tesiwaju pelu egbe orin naa, ki n si di owo ti mo ba ri nibe mu.”

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here