O̩ko̩ àfé̩só̩nà mi ni adúró-tini ló̩jó̩ ìsòro – Solidstar
Olorin Solidstar ti safihan imoore si afesona re, o gboriyin fun idurosinsin re bi o ti le je wi pe o dojuko akoko ti o le fun odun mewaa.
Amo sa, atejade naa ni o ti fa awuyewuye oro lati odo awon eniyan lori ayelujara.
Ninu atejade naa, Solidstar fi aworan oun ati afesona re lede, ti o si so nipa irora, omije, ati ibanuje okan ti o farada pelu isesi re.
O ko o pe: “Idurosinsin! Fun odun mewaa, gbogbo nnkan ti o ri lati odo mi ni irora, omije ati ibalokanje. Sugbon ko jawo loro mi.”
Nigba ti awon kan n gboriyin fun idurosinsin ati ifarasin afesona naa, awon kan n da Solidstar lebi, fun bi o se fi nnkan ti o n fa iponju ba enikeji re yangan.
Awon elomiran n beere pe ki lode ti o fi je pe nnkan ti ko dara nipa ibasepo won lo toka si, nigba ti awon miran n fi esun aimora ati imotara eni nikan kan an.