Mo nílò àdúrà, isé̩ abe̩ kíndìnrín tí mo s̩e kò yo̩rí sí rere – TG Omori
Mary Fágbohùn
Gbajumo adari fonran orin Naijiria, Thankgod Omori, ti a mo si TG Omori, se ise abe kindinri laipe yi ni Eko.
Adari orin naa safihan eyi ninu atejade kan to fi lede lori X ni Ojobo, o so di mimo pe ise abe naa ni ko yori si rere.
O pe awon afenifere re lati gbadura fun oun, paapaa julo lasiko yii ti o n ba aisan kindinri ja.
O safihan pe kindinri oun baje ni odun to koja.
Omori ko o pe, “Leyin odun kan ti kindinri mi ko sise mo, mo se ise abe asopo fun omiran ni ile iwosan St Nicolas ni Eko, sugbon ko yori si rere. E gbadura fun mi.”