Mi ò tíì setán láti l’óyún – Kassia
Omole Elegbon Agba Naijiria, abala ‘No Loose Guard’, Kassia ti so pe oun ko tii setan fun oyun.
O so eyi nigba to n jiroro pelu oko ati enikeji re lori ero, Kellyrae, ni Ojobo.
Oko re so fun in pe, baba re yoo gbogun ti won lati bi omo leyin ti eto naa ba pari sugbon o fesi pe, oun ko tii setan, o tenumoo pe, won nilo lati wa owo.
Kellyrae: “Ti a ba jade ninu ile, baba re yoo ma yo o lenu lati loyun.”
Kellyrae: “Ko si aaye.”
Irohin jade pe Kassia ati Kellyrae se igbeyawo saaju ki won to lo si ori eto naa.
Awon tokotaya naa ti n gbiyanju lati fi ibasepo won pamo fun awon omole to ku bii ete lori eto naa.