Èyí le o, ìdílé ẹlẹ́ni márùn-ún kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹ májèlé mọ́’nú oúnjẹ
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ògédé èèyàn tí Ọlọ́run pamọ́ nìkan ló bọ́ lọ́wọ́ ewu.Àṣamọ̀ yìí kò sẹ̀yìn ìṣẹ̀lẹ̀ tó wáyé nínú ìlú
ìlú kékeré kan tí wọ́n n pè ní Kaura-Wanke, níjọba ìbílẹ̀ Shagari, níìpínlẹ̀ Sokoto, bóṣe kan gbínrín gbínrín látàrí pé ọ̀fọ̀ nlá ṣẹ wọ́n níbẹ̀. Páropáro nìlú ọ̀hún dá báyìí, nítorí tí ìdílé ẹlẹ́ni márùn-ún kan kú lẹ́yìn tí wọ́n jẹ ajílẹ̀ mọ́’nú ọbẹ̀ tí wọ́n jẹ láìpẹ́ yìí. Láti Ọjọ́bọ, ọ̀sẹ̀ tó kọjá, ni àwọn ìdílé náà ti wà lọ́sibítù ìjọba ìpínlẹ̀ tí wọ́n n gba ìtọ́jú lọ́wọ́, ṣùgbọ́n nígbà tó máa fi di ọjọ́ Ẹtì, ọ̀sẹ̀ tó kọjá, ni mẹ́ta lára àwọn mọ̀lẹ́bí náà kú. Nígbà tó tún máa fi di ọjọ́ Àìkú, ọ̀sẹ̀ ọ̀hún, ni àwọn méjì mí-ìn bá tún kú síléèwòsàn ìjọba tí wọ́n ti n gba ìtọ́jú lọ́wọ́.
Kọmiṣanna fun eto ilera nipinlẹ naa, Abilekọ Hajiya Asaba Balarabe, to fidi iṣẹlẹ ohun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Iṣẹgun, ogunjọ, oṣu yii, sọ pe, ‘’Ilu Abuja ni mo wa lasiko ti wọn fọrọ ọhun to mi leti pe idile ẹlẹni meje kan jẹ majele mọ’nu ounjẹ ti wọn jẹ, loju-ẹsẹ naa ni mo si ti ran awọn oṣiṣẹ ileeṣẹ mi lọ sibẹ pe ki wọn gbe wọn kuro lọsibitu ijọba ti wọn wa, ki wọn maa gbe wọn lọ si ọsibitu akanṣe kan to le ṣetọju wọn daadaa, ṣugbọn bo ṣe wu Ọlọrun Ọba lo n ṣe ọla rẹ, awọn marun-un ti pada ku ninu awọn ẹbi naa bayii. Mẹta lo kọkọ ku l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, nigba ti awọn meji kan tun ku lọjọ Aiku, , ọjọ kejidinlogun, niṣoju mi.
‘’Ohun tawọn dokita sọ ni pe kẹmika to wa ninu ounjẹ ti wọn jẹ ti ba ọpọ ẹya ara wọn jẹ kọja atunṣe ko too di pe wọn gbe wọn wa sileewosan awọn’’.
Mọlẹbi awọn to ku ti dupe gidi lọwọ kọmiṣanna naa fun bo ṣe tete gbe igbesẹ gidi lori awọn idile naa, bo tilẹ jẹ pe marun-un lo ti ku ninu wọn bayii, tawọn kan si ti n gba itọju lọwọ nileewosan ijọba kan to wa nipinlẹ naa bayii.