Akẹ́kọ̀ọ́ tí kò bá tíì pé ọdún méjìdínlógún kò ní lè ṣe ìdánwò WAEC àti NECO mọ́ —– ljoba
Ṣé wọ́n ní èèyàn tí kò
gbọ́ tẹnu ẹ̀gà ni yóó pè é lẹ́yẹ aláròyé.
Ìjọba àpapọ̀ ti kéde pé akẹ́kọ̀ọ́ tí kò bá tíì pé odún méjìdínlógún kò ní láánfàní láti kópa nínú ìdánwò àṣekágbá ilé ẹ̀kọ́ girama, NECO àti WAEC mọ́.
Fẹ́mi Akínṣọlá
Minisita fun eto ẹkọ lorilẹede Nàìjíríà, Ọjọgbọn Tahir Mamman lo sọ eyi nigba to n sọrọ pẹlu ileeṣẹ tẹlifisan Channels lọjọ Aiku, ọjọ Kẹdọgbọn, oṣu kẹjọ,. ọdun 2024.
Ọjọgbọn Mamman ṣalaye pe ijọba apapọ ti pa a laṣẹ fun gbogbo ajọ to n risi idanwo WAEC ati NECO lati ri pe wọn tẹ le aṣẹ ijọba yii.
Bakan naa lo ni igbesẹ ijọba apapọ yii kii se igbesẹ tuntun.
O fikun ọrọ rẹ pe iye ọjọ ori fun akẹkọọ lati se idanwo idanwo JAMB ati wọ ile ẹkọ giga fasiti si wa ni ọdun méjìdínlógún.
“Ọdun méjìdínlógún ni ọjọ ori , nnkan ti a sọ ninu ìpàdé wa pẹlu JAMB ninu oṣu keje ni pé a fi ààyè sílẹ̀ ní ọdún yìí láti jẹ́ kí àwọn òbí mọ nípa ìgbésẹ ìjọba .
“Idanwo Jamb gba awọn akẹkọọ ti ojọ ori wọn ko ti to ẹni ọdun méjìdínlógún ni ọdun yii sugbọn wọn o ni igba bẹẹ ni ọdun to n bọ.
“Ajọ Jamb yoo ri pe ọjọ ori awọn akẹkọọ ti wọn yoo wọ, ile ẹkọ fasiti pe ọdun méjìdínlógún.
“Ti ẹ ba se isiro ọjọ ori to yẹ ki awọn akẹkọọ lo ni ile ẹkọ, apapọ ọdun naa yoo jẹ ọdun mẹtadinlọgbọn ati abọ, bẹrẹ lati igba ewe wọn.
“Ìgbẹ́sẹ̀ yìí kì í ṣe ìgbésẹ tuntun, láti fi tako ọ̀rọ̀ kan tí àwọn èèyàn sọ.”