Wó̩n ní kí n máa seré mó̩ nítorí P-Square – Flavour
Mary Fágbohùn
Olorin alujo Naijiria, Chinedu Okoli, ti a mo si Flavour N’abania, ti seranti igba kan ri ti won ni ko kuro lori itage, nitori pe P-Square fe sere.
Flavour so eyi laipe yi lori eto ‘In My Opinion’.
Gege bi o se so, o bere ise orin re gege bi olutosona orin ati onilu ni ile ijosin.
Amo sa, leyin ipabade pelu P-Square ise orin re gba ayipada.
O ni, “Mo ranti ojo kan pelu P-square, nigba ti won gbe orin “Temptation’ jade. Won n se agbelaruge ere kaakiri, eni to si n ba won se agbelaruge ere naa mu won wa si gbagede City Centre ni ilu Enugu.
“Pelu gbagede yi, mo ti ni awon afenifere; gbogbo eniyan ni o maa n wa nibe ni opin ose.
“Nigba ti eni to n se agbelaruge yi mu Psquare wa, logan ti P-Square de; alakoso so pe, ‘E n le o, e pa nnkan ti e n se.ti’.
“Mo pa, mo fi gbohungbohun sile, mo lo jokoo. Nigba naa ni Paul ti P-square mu gbohungbohun naa o si so wi pe, ‘This na temptation’ (eyi ni adanwo) gbogbo ibe daru.”