Wó̩n ń lépa è̩mí mi o – Adeyinka Alaseyori

Wó̩n ń lépa è̩mí mi o – Adeyinka Alaseyori

Mary Fágbohùn

Olorin ihinrere Naijiria, Adeyinka Alaseyori, ti figbe ta pe awon kan lori ayelujara n wa lati gba emi oun.

Ni ori abala wo mi ki n wo o kan to se lori Instagram, Alaseyori safihan pe orisiirisii iyolenu ni oun n koju lori ayelujara lati bii osu mefa seyin.

Olorin Oniduro naa se’kilo pe awon ti n ro iku kan oun, n fa ibanuje wa sori ara won ni.

“Maa ri oro asoye awon miran, maa rerin. Maa ri epe, maa rerin. Mo ri opolopo to n fe ki nnkan aburu sele si mi, mo rerin. Mo kan n fi yin rerin ni. Nitori pe enikeni to ba ro iku ro mi kan n ka ojo iku fun ara re ni.

“Ti e ba ro iku ro mi, e n pe fun iku gbigbona ni. Ti e ba ro pe ohun ti o to si mi ni iku, eyin naa fe ku.

“Ti e ba fi ateranse sowo si mi tabi ti e pe awon eniyan mi lati sepe fun mi, iku yoo le yin. Ti e ba dide tabi jokoo e n pe fun iku. Mi o fe ateranse yin. Ayanmo mi ko ni ku. Mi o ni di alailegbese. E koo sile, o je eewo fun emi Adeyinka Alaseyori.

“Ti enikeni ba pejo lati ro iku ro mi, ko ni fise bi won ba se po to, koda bi won je wooli, angeli iku yoo maa tele won kiri. Aye yi nika o. O je ohun inira, o si ba ni ninu je. Opolopo nnkan ni o n lo ti enikan o mo,” o ma se o!

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here