Ènìyàn burúkú ni àwo̩n tó̩ò̩gì ìjú Ìshàgá – Portable

Ènìyàn burúkú ni àwo̩n tó̩ò̩gì ìjú Ìshàgá – Portable

Alawuyewuye olorin Naijiria Portable ti figbe ta leyin ti awon omo adugbo se ikolu sii nibi ayeye kan ni Iju-Ishaga, ipinle Eko, ni ojo Aiku.

Nigba to n soro leyin isele naa, olorin naa, ninu fonran kan to n lo kaakiri lori ayelujara, fihan pe oun sese pupo.

Ninu atejade to fi lede lori Instagram, o salaye pe oun wa nibi ayeye naa lati sajoyo pelu ore oun ti o n ta oko ayokele sugbon ti oun kanju pada lo si ile pelu apa lara leyin ti awon kan ri ihuwasi oun gege bi nnkan ibinu.

Portable, eni ti ori ko yo ninu ikolu naa, figbe ta pe won ko tii ri awon omo ise oun.

Nigba to n pe eni to lo ba se ajoyo pe ki o so fun awon omo adugbo naa lati da nnkan ini oun ti won ji pada, olorin naa so pe awon si n wa awon olorin oun.

O safihan pe awon to se ikolu naa ji opolopo ohun eso ara, kaadi igbowo (ATM card), ero agbelowo meji to je ti alakoso re, ati awon nnkan miran.

Ikolu naa waye leyin ti o lo sori ayelujara lati sajoyo ojo ibi omo Babyluv akoko.

O ko o pe: “Wahala laasigbo nla ni Iju-Ishaga. A lo sajoyo pelu @lincon_orn eni to n ta oko. Laarin adugbo nibi ti a ti n sere, nibe ni awon egbon adugbo ti ya bo wa, a o ti ri awon omo ZEHNATION.

“Won se ikolu si awon omokunrin mi leyin ti mo ribi sa asala… @lincon_orn jowo ba mi so fun awo egbon adugbo lati da ero agbelowo @iam_sexyshay’s meji ati kaadi igbowo mi pada. A ti ri ero agbelowo @dullarboi ati oko ayokele re sugbon a o ri oun funra re.

“Mi o ti ri @bamidola_ a gbo pe won se ikolu sii. Awon olorin mi ti a o ti ri niyi o. Olorun ko ni doju ti wa. Eni ibi ni awon eniyan yi, bee ni won se mu mi. Awon Egbon adugbo yi gba egba orun olowo iyebiye mi ati yeeti mi ti won fi wura se leyin ti mo fi ife han won ti mo si fun won ni owo. Won tun fe gba apo mi. Se afenifere ni won tabi ota?”

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here