Bílíò̩nù kan náírà fún ìjo̩ K&S – Davido

Bílíò̩nù kan náírà fún ìjo̩ K&S – Davido

Mary Fágbohùn

Gbajumo olorin takasufe Davido ti fesi lori iwa oninure ti baba re hu nipase sise itore bilionu kan naira fun ijo Kerubu ati Serafu (Centenary Endowment Fund of the Cherubim and Seraphim (C&S) Church).

Eyi waye nitori pe Adedeji Adeleke se itore yi ni iranti iya re, Esther Adeleke, nigba ti won n se ayeye iranti re.

Davido gboriyin fun baba re lori akitiyan ife si omoniyan, o ni o feran lati satileyin fun ile ijosin ati eto eko.

O ko o ni abala oro asoye pe: “Ohunkohun ti o ba niise pelu ile ijosin ati eto eko, e ma se iyonu, e ti ri owo.”

Olorin naa tun safihan iwuyi ti o ni si baba re lori Instagram, wi pe, “Baba mi owon, o je iwuri fun mi lojoojumo. Mo feran okunrin yi.”

Ayeye itore naa ni awon eniyan nla peju pese sibe, awon Gomina ati awo̩n o̩to̩ku ilu.

 

 

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here