Mi ò ní ìmò̩lára ìfé̩ – Omah Lay
Olorin takasufe Omah Lay ti soro lori adojuko re ni ile ise orin.
Olorin ‘Boy Alone’ naa so pe oun ko ni imolara ife paapaa julo lati odo awon onirohin ati awon asobode ile ise orin.
Ninu iforo-wani-lenu-wo to se pelu Amazon Music, Omah Lay salaye pe lati sa asala kuro ninu ohun ti o sapejuwe bii ‘aridaju ibanuje’, oun n gbe ninu aye irokuro ni opo igba.
“Mo ni awon afenifere, awon ebi ati awon alabasisepo sugbon mi o ni imolara ife paapaa julo lati odo awon oniroyin ati awon eniyan ti won pe ara won ni asobode,” ni o so.
“Eyi je nnkan ti mi o soro nipa re ri. Mo je olorin to n gbe ninu aye irokuro. Bi ida aadorun-un igba ni mo fi ori fi ibugbe.”
Omah Lay tun so pe jije omo Naijiria ati lilo irinajo pelu iwe irinna Naijiria soro gidi.
“Lilo irinajo paapaa julo bii omo Naijiria ati pe o ni iwe irinna Naijiria lowo, mo ti ri bi aye se le to.
“Awon osise ibudo isilo nigba miran maa n se mi bi ko se ye nitori iwe irinna Naijiria di igba ti mo ba so fun won pe emi ni Omah Lay ki isesi won si mi to yipada.”