Inú mi dùn pé mi ò jáwé olúborí ní ilé Big brother Afrika – Beverly Osu
Osere tiata Beverly Osu ti seranti igba to wa lori eto Ile Elegbon Agba Afrika ni odun 2013.
Ninu ijiroro to se laipe yi pelu mohunmaworan HIPTV, o ni oun dupe nitori pe oun ko jawe olubori ninu idije naa.
Osu fi se awada pe iya re ko fe ki o gba ebun owo naa, nitori iberu pe yoo mu sina.
O fi ibale okan re han ni bi ko se jawe olubori, o toka si pe oun le ma ni ogbon to ye lati lo owo naa daradara ni igba naa..
O ni: “Inu mi dun pe mi o jawe olubori, nitori ko si nnkan ti mo fe se ti maa fi jawe olubori.
”Ti awon afenifere ba n gbadura fun mi lati jawe olubori, obinrin ti o bi mi n gbadura si Olorun pe ‘Ti o ba je pe omo yii yoo gba ebun owo yi ti yoo si mu sina, nitori pe o ti sina ri,. Ti o ba je pe yoo jawe olubori lati gba owo yi ti yoo si sina, Olorun jowo mase fun.’”
“Akoko Olorun lo dara ju, inu wa dun nitori pe bayii a ti ri owo to ju bee lo. Ti mo ba gba owo naa, mo le ma mo nnkan ti maa fi se. Mi o ti ni iriri lati lo o fun nnkan ti yoo ni ipa rere ninu aye mi, bee ni, niwon igba ti mo n rise bayii”
O tesiwaju lati so pe ori oun n wu fun bi aye oun ati ise oun ti se dara sii lati igba naa.