Yhemolee segbeyawo alarede ni ile ejo [FONRAN]
Gbajumo eda ni ile ijo Idowu Adeyemi, ti a mo nibi ise si Yhemolee, ti se igbeyawo alarede pelu ololufe re, Tayo B.
Tokotaya naa se igbeyawo ni ile ejo ni ojo Aje.
Tayo B fi fonran ati aworan ayeye naa ti awon ebi ati ore timotimo peju pese sibe lede ni ori itan Instagram re ni ojo Isegun.
Ninu fonran to ti n lo kaakiri lori ayelujara, tokotaya naa ni a ri ti won di owo ara won mu bi won se n jeje fun ara re.
E ranti pe Yhemolee denu igbeyawo ko Tayo ni osu keje.
Iroyin jade pe awon mejeeji ti jo wa fun igba pipe sugbon ti won tuka ni odun 2023, lori esun aisooto.
Sugbon won pada tu ina ife won da leyin ti Yhemolee rawo ebe si Tayo ni gbangba ni ibere odun yi.