P-Square: Peter Obi se ìpàdé pè̩lú Mr P àti Rudeboy

P-Square: Peter Obi se ìpàdé pè̩lú Mr P àti Rudeboy

Oludije fun ipo Aare labe asia egbe oselu Labour Party ninu eto idibo odun 2023, Ogbeni Peter Obi, ti ba awon olorin meji, P-Square, Peter ati Paul Okoye se ipade.

E ranti pe Peter Okoye, eni ti a mo si Mr P, ni ojo Aje ko iwe si arakunrin re, Paul Okoye, lori aawo ti o wa laarin won.

Rudeboy, ninu iforo-jomi-toro oro to se laipe yi, fi esun kan arakunrin re pe o ko iwe ijejo si ajo to n ri si eto oro aje ati iwa odaran (Economic and Financial Crimes Commission, EFCC), lati fi oun si atimole.

Sugbon Peter, ninu leta ti o ko ni ojo Aje, so pe oun ko mo nnkankan nipa esun naa, o ni ilepa oun ni lati so ooto to wa leyin ile ise kan, Northside Music, to da bii pe, Jude Okoye, iyawo re, Ifeoma ni si ipamo.

Amo sa, ninu ohun to dabii ipade ibalaja naa, Peter Obi ni a ri ninu fonran to n lo kaakiri pelu awon olorin mejeeji ni irole ojo Isegun.

Rudeboy fi fonran naa lede ni oju awe Facebook pelu oro ifori pe “E se o, Olorun yoo bukun yin sa, P.O. @peterobigregory #enididarajulo.”

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here