Mark Angel so̩ fún àwo̩n ènìyàn pé mo ti kú’ – Denilson Igwe

Mark Angel so̩ fún àwo̩n ènìyàn pé mo ti kú’ – Denilson Igwe

Gbajumo aderinposonu ati onifonran Denilson Igwe ti fi esun kan akegbe ati ojugba re, Mark Angel, pe o so fun awon eniyan pe oun ti ku leyin aawo to be sile laarin won.

O fi esun yi lede nigba to farahan lori eto ‘The Honest Bunch’.

Igwe wi pe, “O [Mark Angel] so fun awon eniyan pe mo ti ku. O ni fonran kan to se nipa re. O wi pe, ‘Denilson ti ku o!’ Nigba ti won bii leere, o ni mo ti ku.

“Enikan pe mi laipe yi lati wadii boya mo ti ku nitooto. Mo si so fun un pe mo wa laaye.”

Denilson Igwe wi pe awon ojugba Mark miran, Emmanuella ati Success, yoo wa sori eto naa ni ojo kan lati wa so nnkan ti “oju won ri” lodo re.

Mark Angel ni ko tii fesi si esun yi.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here