Gbádùn ayé re̩, ò̩la ò dájú, ni Alesh Sanni so̩
Mary Fágbohùn
Osere tiata, Alesh Sanni n kedun ipapoda arakunrin re lojiji.
Lori Instagram, Sanni safihan ibanuje re, o ni ko si ohun to ni itumo si oun mo.
O woye bi ile aye se je fun iwon igba die, o tokasi bi enikan se le e wa laye ni owuro sugbon ko ma si mo ni osan.
Sanni ro awon afenifere re lati je igbadun aye won, nitori pe ola ko daju.
O tokasi si bi opolopo eniyan se maa n ni afojusun, sugbon ti iku yoo de lojiji, ti yoo si so gbogbo re si nnkan ti ko ni itumo.
O tesiwaju ninu riro awon alatele re lati fe awon ti o feran won, pelu bi isele to n ba ni lokan je se je ohun ti enikan ko lero re.
O ko o pe: “Omo. Ko si nnkan to ni itumo si mi mo. Haaaa. Ni isinsinyi, enikan wa laaye. Ka tun to gbo, o ti lo. Ki lode? O gbodo je igbadun aye re o nitori pe ola ko daju. SUN N RE ARAKUNRIN.
“E jowo, ki lo wa ni aye gan-an? Mo fe rin irinajo kaakiri aye, mo fe fi owo pamo, mo fe ra ile, mo fe se ti ibi ati ti on… omooooooooo gbe igbe aye re fun oni oooo …. Haaaaaaaa haaaaaa ko tile ye mi mo”.