E̩ má se bá Maria Chike jà’ – Mercy Eke sè’kìlò̩
Mary Fágbohùn
Onirawo eto mohunmaworan, Mercy Eke ti se’kilo pe ki awon afenifere ma se ba akegbe re, Maria Chike ja.
Gege bi o se so, biba iya omo kan naa ja lewu nitori yoo lo gbogbo to ba wa lowo re lati ba eni naa ja.
O ni, isinje Chike lo mu ki oun fi oju awe ayelujara, Snapchat sile fun igba die.
Ni ori X re ni ojo Isegun, o ko o pe; “Nitori ara re, ma se ba Maria Chike ja. O ni idi… Gbogbo ohun to ba wa ni ikawo re ni yoo fi ba o ja.
“Ni se lo n le mi kiri lori SnapChat… mo fi ibe sile dun… e ma da si oro re.”
Ore Eke ati Chike bere nigba ti won jo wa ni ile Elegbon Agba Naijiria abala ‘Pepper Dem’ ni odun 2019. Won si je ore lati igba naa.