Ó rò̩ mí ló̩rùn láti ko̩rin lédè Yorùbá – Asake
Mary Fágbohùn
Olorin takasufe, Asake ti safihan pe o ro oun lorun lati korin pelu ede Yoruba nigba ti o n ba awon afenifere re soro lori eto wo mi ki n wo o ti o se pelu won lori Instagram.
O so pe oun le e korin pelu ede Geesi, sugbon o n ro pe o ro oun lorun lati lo ede Yoruba.
Asake tenumoo pe awon afenifere ti ko ba moriri orin re ni Yoruba ni ki won ma se gbo orin re mo.
O wi pe: “O ro mi lorun gidi lati korin pelu ede Yoruba, kii se pe mi o le korin ni ede Geesi. Ti o ba gba temi, gba temi pelu Yoruba mi. Bi bee ko, ma gba temi”.
Awo orin Asake meteeta , “Mr Money With The Vibes”, “Work of Art”, ati “Lungu Boy”, ni ede Yoruba ti leke.
Orin re ti gbogbo igboro gba “Amapiano” ni a fa sile fun ife eye Grammy, bo tile je wi pe o korin ni ede Yoruba.