Ẹ̀ má fọ́nwó kiri o,ẹ̀wọ̀n ò jọlé– Bobrisky doní wàásù òjijì
Mary Fagbohun
Gbajúmọ̀ ajísebióbìnrin, Idris Okuneye, ti a mọ̀ sí Bobrisky, ti gba àwọn ọmọ Nàìjíríà nímọ̀ràn láti máṣe lo owó náírà ní ìlòkulò tàbí kí wọ́n di onílé ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Bobsrisky sọ bẹ́ẹ̀ ni kété tó jáde ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ní ọgbààtúnrọ
Ẹ ó ranti pe Boborisky ni o fi ẹwọn osu mẹfa gbara fun titabuku owo naira.
Ninu ijomitoro ọrọ kan pẹlu mohunmaworan GoldMyneTV, o rọ awọn ọmọ Naijiria lati tẹle ofin ijọba.
”E mase fọn owo kiri, ayaafi ti ẹ ba fẹ di onile ni Kirikiri.”
“Kiise nipa pipa eniyan tabi iwa ọdaran miran, nnkan kekere bi eleyi le e gbe ọ debẹ.
“Mo kan n dojukọ awọn ọrẹ mi ti wọn duro ti mi, mo dupe gidi. Mi o ronu nipa elomiran.”