Wizkid je̩ ìwúrí fún mi, ó pé̩ tí mo ti ń wá ò̩nà láti ko̩rin pè̩lú rè̩ – Asake
Olorin takasufe, Ahmed Ololade, ti a mo si Asake, ti safihan pe akegbe re olugbafe eye Grammy, Wizkid je okan lara awon iwuri re lati korin.
O so eyi di mimo nigba to n soro lori orin to ko pelu olorin ‘Ojuelegba’ ninu awo orin re tuntun to se ni yara igborinsile, ‘Lungu Boy.
Ninu akiyesi orin ti won ko papo lori ise agbese naa, ‘MMS’, ni oju awe ti a ti n gbo orin, Asake fihan pe o ti pe ti oun ti ni itara lati korin pelu Wizkid.
O ko o pe: “Kiise asiri pe Wizkid je okan lara ohun to se iwuri fun mi lati korin. Gege bi omode olorin to n gbiyanju ni Eko, Mo ti n duro fun orin ti o to nitori naa nigba ti anfani de, kii se seresere.
“‘MMS’ duro fun ‘Mr Money Sound’ o salaye irinajo orin mi.”