Wo ìgbésẹ̀ tí o lè gbé láti ṣí síìmù rẹ bí wọ́n bá dèna rẹ̀ láti fi pè

Wo ìgbésẹ̀ tí o lè gbé láti ṣí síìmù rẹ bí wọ́n bá dèna rẹ̀ láti fi pè

Ọrẹ Òtítọ́jù

Lọ́jọ́ Àìkú tó kọjá yìí, ọjọ́ kejìdínlọ́gbọ̀n, oṣù keje, ọdún 2024, ni àwọn ilé-iṣẹ́ ìbánisọ̀rọ̀ kan gbẹ́sẹ̀ lé àwọn ojú òpó ìbánisọ̀rọ̀ kan lórílẹ̀ èdè Nàìjíríà.

Eyi jẹ ara igbesẹ to kẹyin lati gbegidina ipe awọn to kọ lati so nọmba NIN wọn papọ mọ siimu wọn.

Titi di asiko yii ni ọpọ araalu n kọminu lori bi awọn ileeṣẹ ibanisọrọ naa ṣe gbegidina awọn nọmba ibanisọrọ awọn onibara wọn, paapaa awọn ti wọn ko tii so nọmba idanimọ NIN papọ mọ siimu wọn.

‘Ki lo ṣẹlẹ’, abi foonu mi ti bajẹ ni’…wọnyi ati awọn ọrọ kayeefi miran lo n jade lẹnu ọpọ awọn onibara MTN, nigba ti wọn ṣakiyesi pe awọn ko le pe jade, bẹẹ si ni awọn ko le yẹ iye owo ku lori siimu wọn, pẹlu awọn nnakn miran.

Inu oṣu kejila, ọdun 2020 ni ijọba apapọ Naijiria paṣẹ fun gbogbo awọn ileeṣẹ eleto ikansira-ẹni bii MTN, Airtel, Glo, Etisalat ati awọn miran lati so nọmba idanimọ (NIN) awọn onibara wọn papọ mọ siimu wọn.

Eyi ni ijọba sọ pe yoo fopin si iwa ijinigbe, iṣẹkupani, igbesunmọmi ati oniruuru iwa ọdaran miran.

Ijọba apapọ sọ pe ki awọn ileeṣẹ eleto ikansira-ẹni yii gbegidina ipe awọn onibara wọn, ti wọn ba kọ lati tẹle ilana laarin gbedeke ọjọ ti wọn fi sita.

Awọn onibara miliọnu mẹtalelaadọrin ni awọn ileeṣẹ eto ikansira-ẹni yii dawọ ipe jade wọn duro, ti wọn ko si tun le ṣe ohun miran.

Igba mẹsan ọtọọtọ ni ijọba apapọ fi wọgile gbedeke ọjọ ti wọn pa a laṣẹ fun awọn ileeṣẹ ikansira-ẹni wọnyi, lati le gba awọn eeyan laaye lati kopa ninu eto naa, iyẹn ṣaaju ọjọ kẹrin, oṣu kẹrin, ọdun 2022

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here