Ẹ̀yin alága ìjọba ìbílẹ̀ Ọ̀yọ́ tí ẹ tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ, ẹ má jẹ́ kí gómìnà ran yín lẹ́wọ̀n – APC
Lórí awuywuye ibi tó yẹ kí ìjọba àpapọ̀ máa san owó ìdàgbàsókè ìjọba ìbílẹ̀ sí tó ń jà rànìnrànìn ní ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́, agbẹjọro kan ti sọ pé ó lòdì sí òfin kí ìjọba Oyo tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́.
Tó bá wu àwón alága ìbílẹ̀ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kí wọ́n dá ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ́ sílẹ̀, wọn ò lè yí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ padà.
Nígbà tó ń bá akọ̀ròyìn sọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀ náà, Monday Ubani (SAN) sọ pé kò sí ohun tí ìjọba Ọ̀yọ́ tàbí àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ rẹ̀ lè ṣe lẹ́yìn ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà.
Tó bá wu àwọn alága ìbílẹ̀ ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ kí wọ́n dá ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ́ sílẹ̀, wọn ò lè yí ìdájọ́ ilé ẹjọ́ padà.
Ó ní láti nǹkan bíi ọgbọ̀n ọdún óle tí òun ti ṣiṣẹ́ agbẹjọro, òun kò tíì gbọ rí pé ìjọba ìpínlẹ̀ tàbí ìbílẹ̀ kankan gbénà wojú ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ ní Nàìjíríà láìíṣe pé wọ́n pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn.
Ubani sọ pé “ó jẹ́ àpẹrẹ tó léwu gidi nígbà tí ìjọba ìbílẹ̀ bá sọ pé òun kò ní tẹ̀lé ìdájọ́ ilé ẹjọ́.