Ayẹyẹ ọdún Ọ̀ṣun Òṣogbo gbérasọ

Ayẹyẹ ọdún Ọ̀ṣun Òṣogbo gbérasọ

Fẹ́mi Akínṣọlá

Ayẹyẹ ọdún Ọ̀ṣun Òsogbo tó gbérasọ lónìí ló bẹrẹ pẹ̀lú Ìwọpópó. Ìwọpópó jẹ́ ayẹyẹ tó máa ń ṣaájú Ìboríadé àti Ọ̀ṣun Òsogbo.

Iwopopo jẹ ọjọ ti wọn maa n fi wure fun gbogbo ilu ati fun gbogbo eeyan to maa wa sibi ayẹyẹ ọdun Ọṣun Osogbo.

Ọdun Ọṣun Osogbo jẹ ayẹyẹ to maa n waye ni ọdọọdun lati ni ilu Osogbo, olu ilu ipinlẹ Ọṣun.

Nibi ayẹyẹ ni wọn ti maa n bọ Ọṣun, to jẹ ọkan lara awọn oriṣa ilẹ Yoruba.

Ọṣun gẹgẹ bi itan ṣe fidi rẹ mulẹ jẹ ọkan lara awọn iyawo Sango.

Ninu ọrọ rẹ, Kabiyesi Ọba Jimoh Olanipekun, Ataoja ti ilu Osogbo sọ pe iwopopo jẹ olulana fun ayẹyẹ ọdun Ọṣun Osogbo.

Ọba Jimoh Olanipekun ṣalaye iwopopo kii ṣe ọdun ṣugbọn o jẹ atọna ibẹrẹ ọdun Ọṣun Osogbo to tun jẹ ọjọ pataki ti wọn maa n fi wure fun gbogbo eeyan n to bọ wa si bi ayẹyẹ ọdun naa.

Lasiko iwọpopo yii ni omidan ti yoo ru igba fun ọdun naa yoo ti gba igba lọ si odo Ọṣun.

Osunyemi Ifabode to jẹ Baba Orisa ti ilu Osogbo sọ pe pataki ọdun Ọṣun Osogbo kii ṣe fun awọn ọmọ bibi ilu Osogbo tabi ipinlẹ Ọṣun nìkan bikoṣe ọdun idupẹ fun gbogbo ọmọ kaaarọ-o-o-jire patapata.

Osundara Oyawale, iya Ọṣun ti ilu Osogbo ni ọdun naa eyi ti gbogbo eeyan maa n bere ohun rere ati wi pe, o jẹ ọdun ti Arugba yoo ru ibi danu, ti Kabiyesi yoo si wure fun gbogbo ilu ati fun gbogbo eeyan to peju pesẹ sibi ayẹyẹ naa.

Osundara tun fi kun ọrọ rẹ wi pe ọdun Ọsun Osogbo yatọ si ọdun aṣa sugbọn o jẹ ọdun adura ati iwure lati ẹnu Kabiyesi si gbogbo eeyan patapata.

Ọpọlọpọ eeyan lo peju pesẹ sibi eto Iwopopo lati ṣami ibẹrẹ ọdun Ọṣun Osogbo ti ọdun 2024.

Kaakiri agbaye ni wọn ti maa n ṣe irinajo wa lati kopa nibi ayẹyẹ ọdun Ọṣun Osogbo.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here