Àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ Oyo tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ, wọ́n ní kí owó àwọn wà lápò ìjọba ìpínlẹ̀

Àwọn alága ìjọba ìbílẹ̀ Oyo tako ìdájọ́ ilé ẹjọ́ tó ga jùlọ, wọ́n ní kí owó àwọn wà lápò ìjọba ìpínlẹ̀

Fẹ́mi Akínṣọlá
Báyìí làá ṣe nílé e wa, èèwọ̀ ibòmí-ìn ni, èyí ló bí n tí Ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ sọ pé láá ,òun kọ ìdájọ́ ilé ẹjọ́ gíga kan tó pàṣẹ pé ìjọba ìpínlẹ̀ àti ìjọba ìbílẹ̀ kò gbọdọ̀ máa lo àpò ìṣúná kan náà mọ́.

Ṣaaju ni gomina Seyi Makinde ti kọkọ bu ẹnu atẹ lu idajọ ọhun, to si sọ pe kii ṣe ijọba apapọ ni yoo maa la le awọn ipinlẹ lọwọ lori bi wọn ṣe maa na owo wọn.

Eyi lo n waye lẹyin ti adajọ agba Naijiria, Lateef Fagbemi (SAN) pe ẹjọ lori ọrọ ọhun lọna ati fun awọn alaga ijọba ibilẹ lominira lati maa na owo wọn bo ba ṣe wu wọn.

Idajọ ile ẹjọ to ga julọ naa sọ pe ijọba ipinlẹ ko lagbara labẹ ofin lati maa ṣakoso owo ti ijọba ibilẹ yoo maa na fun atunṣe ilu.

O ni iwa naa ko ba ofin mu rara.

Wayi o, iroyin to n tẹ wa lọwọ ti sọ pe gbogbo awọn alaga ijọba ibilẹ to wa nipinlẹ Oyo ti fẹ yapa kuro ninu ALGON, lọna ati ṣatilẹyin fun Makinde.

Ninu atẹjade kan ti adari awọn alaga ijọba ibilẹ Oyo, Sikiru Sanda fi lede, o ni gbogbo wọn fọwọ si ohun ti Makinde ba sọ ati igbesẹ to ba gbe lori ọrọ naa.

Eredi igbesẹ awọn alaga ọhun, gẹgẹ bi wọn ṣe sọ ni pe Makinde jẹ adari rere to fi apẹrẹ rere silẹ, o si ti ṣe ọpọ aṣeyọri lati igba to ti gori alefa gomina.

Awọn alaga naa tun ti fẹnuko lati da ẹgbẹ tuntun mii silẹ, eyii ti kii ṣe ara ALGON, lọna ati tẹsiwaju iṣẹ wọn ni sinsin araalu.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here