Òfin fààyè gba ìwọ́de ita gbangba, àmọ́ a ò lè gbà kí dukia ìlú ó bàjẹ́-Ìjọba Èkó
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ọ̀kan pàtàkì lára ọmọ ẹgbẹ́ òṣèlú APC níìpínlẹ̀ Èkó, tó tún jẹ́ Akọ̀wé fúnjọba ìpínlẹ̀ náà, Abilékọ Abimbọla Salu-Hundeyin, ní àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ lábẹ́ òfin orílèèdè yìí láti ṣèwọ́de ìta gbangba láti fẹ̀hónú hàn sóhun tí kò bá tẹ́ wọn lọ́rùn láàrin ìlú, ṣùgbọ́n kì í ṣe pé kí wọ́n fi dá wàhálà sílẹ̀.
O ni ijọba ipinlẹ Eko ko ni i faaye gba pe ki awọn oni-jagidi-jagan kan waa fọrọ iwọde ita gbangba naa kẹwọ lati doju ija kọ ijọba ipinlẹ gẹgẹ bo ṣe waye nigba EndSARSlọdun 2020, ti wọn da ijọba ipinlẹ Eko ni gbese nla lasiko naa.
O rọ awọn eeyan ipinlẹ Eko pe bi wọn ba tiẹ maa ṣewọde ọhun, ki wọn ṣe e pelu suuru, ki awọn ọmọ ganfe ma ja a gba mọ wọn lọwọ. O ni ki wọn ri i daju pe ọrọ iwọde ita gbangba naa ko di eyi to maa di yanpọnyanrin, ti gbogbo ẹ aa fi dojuru, ti ọrọ yoo si waa di bo o lọ o yago fun mi gẹgẹ bo ṣe ti waye lasiko tawọn ọdọ orileede yii n ṣewọde ita gbangba ti wọn pe ni EndSARS lọdun 2020.
Abilekọ Abimbọla sọrọ naa di mimọ ni Alausa, niluu Ikeja, l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keje, ọdun yii, lasiko to n ba awọn oniroyin sọrọ.
O ni, ‘‘Ipinlẹ Eko ko jẹ ẹnikẹni lowo ifẹyinti rara, gbogbo awọn to fara ṣiṣẹ sin ijọba ni wọn ti gba ẹtọ wọn patapata bayii. Bo o ba ṣiṣẹ pẹlu ijọba Eko, loju-ẹsẹ to o ba ti fẹyinti la ti maa ṣeto owo rẹ fun ọ lai si wahala kankan nibẹ. Gbogbo ọna nijọba n gba lati sọ aye dẹrun fawọn araalu rẹ. ‘’Ohun ti mo n sọ ni pe gbogbo eeyan pata ni wọn lẹtọọ labẹ ofin lati ṣewọde bi wọn ba fẹ, ṣugbọn eyi ti wọn maa ṣe lati fi da rogbodiyan silẹ laarin ilu la ta ko. Igbe aye idẹrun ta a n gbe lorileede yii lo daa, iṣẹ idagbasoke to n waye kaakiri ilẹ wa, paapaa ju lọ, nipinlẹ Eko, ko gbọdọ bajẹ. Ṣe lo yẹ ko maa tẹsiwaju si i, a ko nifẹẹ si ohunkohun to maa da wahala silẹ, paapaa ju lọ bi gbogbo nnkan ṣe n lọ deede lorileede wa bayii’’.