Wàhálà dé bá El-Rufai, àwọn aṣofin ìpínlẹ̀ Kaduna kọjú oro síi
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àpapọ̀ ọmọ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ìpínlẹ̀ Kaduna, ti gba gbajúmọ̀ lọ́ọ́yà ajàfẹ́tọ́ọ̀-ọmọnìyàn nnì, Fẹmi Falana, láti bá wọn wọ́ Gómìnà ìpínlẹ̀ náà tẹ́lẹ̀, Nasir El-Rufai, lọ sílé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn ìkówójẹ tí wọ́n fi kàn án. Ọjọ́bọ, ọjọ́ kẹtàdínlógún, oṣù Keje, ọdún yìí, ni àgbà lọ́ọ́yà ọ̀hún máa bẹ̀rẹ̀ sí í ṣa àwọn ẹ̀sùn tó máa fi kan El-Rufai jọ kó tóó di pé ó máa gba ilé-ẹjọ́ lọ. Àwọn ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn tí wọ́n fi kan gómìnà tẹ̀lẹ̀ ọ̀hún ni pé ó koó owó ìpínlẹ̀ náà jẹ lọ́nà àìtọ́, àti pé ó ṣi ipò rẹ̀ lò lásìkò tó fi wà nípò gómìnà ìpínlẹ̀ náà fún ọdún mẹ́jọ.
Iwadii tawọn aṣofin ipinlẹ naa ṣe nipa iṣakoso ijọba El-Rufai fi han pe o ko obitibiti owo ijọba ipinlẹ naa jẹ lasiko to fi wa nipo.
Bakan naa lawọn aṣofin ipinlẹ naa rọ awọn araalu ọhun pe ki wọn ma ṣe feti sọrọ tawọn oloṣelu ipinlẹ naa kan ti wọn ba El-Rufai ṣisẹ lasiko ijọba rẹ n sọ pẹlu awọn oniroyin.
Atẹjade kan ti alaga igbimo oluwadii ati igbakeji olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Ọnarebu Henry Magaji, fi sita laipẹ yii, ni wọn ti sọ pe, ‘’Ipade pajawiri tawọn oloṣelu ipinlẹ naa ti wọn ba gomina ana ṣiṣẹ pọ ṣe pẹlu awọn oniroyin niluu Abuja, laipẹ yii, ti de setiigbọ wa. Nibi ipade awuruju naa ni wọn ti n naka abuku si igbimọ oluwadii to n ṣewadi nipa ẹsun iwa palapala ta a fi kan El- Rufai, lasiko iṣejọba rẹ nipinlẹ Kaduna. Ara lo n ta wọn ba a ṣe fẹẹ ṣewadii nipa ẹni to gba wọn si iṣẹ, iyẹn gomina tẹle naa. Ọgbọn ti wọn n da ni pe wọn fẹẹ tabuku igbimọ oluwadii naa, kawọn araalu ma baa nigbagbọ ninu wa ni.
‘’Ṣe ni wọn fi ẹtẹ silẹ ninu ipade oniroyin ti wọn pe, wọn n pa lapalapa kiri. Wọn ko ṣoju abẹ nikoo. Bo ba jẹ pe loootọ ni wọn nifẹẹ ipinlẹ Kaduna lọkan, sẹ lo yẹ ki wọn fara ṣiṣẹ fun igbelarugẹ ipinlẹ naa ni, dipo bi wọn ṣe lọwọ ninu iwa palapala to sakoba nla fun idasoke ipinlẹ naa bayii.
‘’Loṣu Kẹfa, ọdun yii, ni awọn aṣofin yii kan an nipa fun El-Rufai pe ki o da biliọnu mẹrindinlọgọrin to loun san fun agbaṣẹṣe kan pada sapo ijọba. Igbesẹ naa waye lẹyin ti igbimọ alabẹṣekele kan ṣewadi nipa ina apa ti ọkunrin naa na lasiko iṣejọba rẹ. Iwadii wọn fi han pe, gomina ana ọhun sanwo tabua naa fun agbaṣẹṣe kan ti ko ṣiṣẹ kankan laarin ilu naa.
‘’Yatọ si eyi, oniruuru awọn iwa ibajẹ ti ko ṣee gbọ seti ni wọn ni ọkunrin yii hu lasiko to fi wa nipo gomina, ta a si feẹ ba a ṣẹjọ lori rẹ’’.
Ni kukuru, awọn aṣofin ipinlẹ naa ti sọ pe awọn ṣetan lati gbena woju gomina wọn tẹlẹ yii. Agba lọọya nni, Fẹmi Falana, ni wọn si ran niṣẹ naa pe ko waa ba awọn wọ ọ lọ sile-ẹjọ.