Obìnrin kan lóbí ọmọ fún mi àwọn tí wọ́n ń f’àwòrán wọn hàn, kìí ṣe ìyàwó mi -Akpabio
Gbọ́láhàn Quseem
Ààrẹ ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin, Sẹ́nẹ́tọ̀ Godswill Akpabio ló ti tọrọ àforíjìn lọ́wọ́ akẹgbẹ́ rẹ̀ obìnrin Sẹ́nẹ́tọ̀ Natasha Akpoti Uduaghan.
Akpabio gbe igbeṣẹ naa lasiko ti apero ile igbimọ aṣofin n lọ lọwọ, lẹyin ọsẹ kan to ti sọrọ ti ọpọ eeyan ni o fi tabuku akẹgbẹ rẹ ọhun
Ninu fọnran kan lori ayelujara lo ti foju han pe aarẹ ile-asofin agba naa ti tọrọ aforijin.
Ohun ti Aarẹ ile igbimọ aṣofin n tọrọ aforijin le lori ni ọrọ kan to sọ fun Sẹnetọ Natasha Akpoti Uduaghan, ẹni to n soju ẹkun idibo aarin gbungbun ipinlẹ Kogi pe, ko ma sọrọ ti ile o ba ti ni ko sọrọ nitori ile igbimọ aṣofin ki ṣe ile igbafẹ alẹ.
Ohun ti Natasha sọ ni “Aarẹ ile, a ko fẹ ki ofin yi ku, a fẹ se atunṣe diẹ si sir.”
Akpabio fesi pada pe,”Sẹnetọ Natasha, ni ile igbimọ aṣofin yii, ile ni lati fun ẹ ni ore ọfẹ ko sọrọ, ki o to le sọrọ sita.”
“Ha, ẹ ma binu, ẹ forijin mi” Akpoti Natasha fesi pa
Ohun ti Natasha sọ ni “Aarẹ ile, a ko fẹ ki ofin yii ku, a fẹ se atunṣe diẹ si sir.”
“Mo mú ilé ìgbafẹ́ alẹ́ wá gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ, nitori awọn èèyàn ibẹ̀ ma n pariwo ju orin tí wọ́n n gbọ́ lọ, awọn èèyàn sì mí gbọ́ lórí ayélujára ni.”