Sé Ládojà náà ṣetán láti jẹ ọba kó tó j’ọba?

Sé Ládojà náà ṣetán láti jẹ ọba kó tó j’ọba?

Gbọ́láhàn Quseem

Ọ̀rọ̀ ifànfà tó wáyé lẹ́yìn ìgbà tí Ọba Adétúnjí gbéṣẹ̀ kí ó tó dipé Ọba Mahood Olalekan Balogun di Olúbàdàn tuntun, ló tún fẹ́ dá wàhálà míràn sílẹ̀ báyìí, ní bí í ìjọba ìpínlẹ̀ Ọ̀yọ́ ṣe gbé ìlànà tuntun kalẹ̀ lórí bí wọn yó ṣe máa j’oyè ọ̀hun.

Gbogbo eeyan lo ti mọ pe gomina tẹlẹri nipinlẹ Ọyọ, Oloye Rasidi Adewolu Ladoja ni yo bọ s’ori apere lẹyin Ọba to ṣẹṣẹ jẹ yi.

Bo tilẹ jẹ pe ṣaaju asiko yi ni wahala ẹni ti ipo Olubadan kan ti kọkọ suyọ ni kete ti ọba ana, Oba Mahood Olalekan Balogun waja.

Ọrọ ọhun lo ti n ja raninraninn fun bi oṣu mẹrin, ki gbogbo rẹ to dopin lọjọ Ẹti, ọjọ Kejila, oṣu Keje, ọdun 2024 nigba ti ‘jọba ipinlẹ Ọyọ gbe ọpa-aṣẹ fun Ọba Akinloye Owolabi Olakulehin, gẹgẹ bi Olubadan kẹtalelogoji.

Ninu iwe ilana eto ti wọn ṣe lọjọ naa, ijọba Ọyọ kọọ sibẹ pe, Oloye to ba ni ade to ga julọ ninu awọn ti ipo ọhun tọ si ni yo j’oye Olubadan.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Gomina ana ni, ‘pinlẹ Ọyọ, Oloye Ladoja ti sọ nigba diẹ sẹyin pe oun ko le de ade kankan, gẹgẹ bi ilana ti ijọba gbe kalẹ.

Ọna lati dena Ladoja, lati ma ṣe di Olubadan ni ijọba gbe kalẹ, ninu agbeyẹwo ilana ti wọn yoo fi maa jẹ oye ọhun ni lọdun 2023.

Abala kẹrin ninu akọsilẹ ilana jijẹ oye Olubadan ti ọdun 1957 sọ pe “ẹni ti wọn yo mu gẹgẹ bi ọmọ oye ti Olubadan tọsi ni oloye ti ipo rẹ ba ga ju .”

Ṣugbọn ninu abala kẹrin agbeyẹwo ilana ti ijọba Seyi Makinde ṣe lọjọ Kẹrinla, oṣu Keje, ọdun 2023, o sọpe: “ẹni ti wọn yo mu gẹgẹ bi ọmọ oye ti Olubadan kan ni ọba ti ade rẹ ga julọ.”

Ko sẹni meji ti ipo rẹ tun ga ju ti Ladoja lọ ninu awọn to n jẹ oye Olubadan bayi, ṣugbọn ti baba naa ti kọ jalẹ wi pe oun ko le ba wọn de ade paali.

Ohun to sunmọ ni pe, Oloye Ladoja le ma ni anfaani lati de ipo Olubadan ti
ilana yi ba di mumu sẹ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here