Ìjọba orílẹ́-èdè UAE ti gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de físà ọmọ Nàìjíría.
Gbọ́láhàn Quseem
Mínísítà ètò ìròyìn àti ìlanilọ́yẹ̀ ní orilẹ̀-èdè Nàìjíríà, Ọ̀gbẹ́ni Mohammed Idris ti sọ́ di mímọ̀ pé àwọn ọmọ Nàìjíríà ti l’ànfààní láti gba físà lati rìnrìn-àjò lọ sí orílẹ̀-èdè United Arab Emirates(UAE) báyìí lẹ́yìn tí ìjọba orílẹ́-èdè naa ti gbẹ́ṣẹ̀ kúrò lórí òfin tó fi de físà ọmọ Nàìjíríà.
Minisita ṣalaye ọrọ naa fawọn akọroyin n’ile-iṣẹ ijọba niluu Abuja, o ni igbesẹ naa waye lẹyin ti ijọba apapọ orilẹ-ede Naijiria s’asọye pọ pẹlu orilẹ-ede UAE lori ọrọ fisa ọhun.
Minisita ni, ijọba Naijiria ti n ba ijọba orilẹ-ede UAE sọrọ naa tipẹ, lori bawọn ọmọ Naijiria yo ṣe l’anfaani pada lati maa gba fisa lati rinrin-ajo lọ si orilẹ-ede UAE ọhun.
‘’ Ọjọ-Aje, ọjọ kẹẹdogun osu yi ni ibuwọlu adehun lori ọrọ naa waye.
Lati oni lọ, awọn ọmọ Naijiria to ba fẹ rinrin-ajo lọ si orilẹ-ede UAE ti lanfaani lati ṣe bẹẹ bayi i,” minisita eto iroyin lo fi kun ọrọ rẹ bẹẹ.
Ti ẹ o ba gbagbe, ọdun 2022 ni ijọba orilẹ-ede UAE fofin de fisa awọn ọmọ Naijiria lọ si orilẹ-ede naa.