Ọ̀rẹ̀ tan ọ̀rẹ́ rẹ̀ pa nítorí àpò aàgbàdo mẹ́ta
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àtúnbọ̀tán ayé ń kànkùn gbọ̀ngbọ̀n gbogbo n tí ò ṣẹlẹ̀ tẹ́lẹ̀ rí tí wá fẹ di bárakú àwùjọ.
Títí daàsìkò tí a ṣe àkójọ ìròyìn yìí ọ̀dọ̀ àwọn ọlọ́pàá agbègbè Jalingo-Daddawa, nipinlẹ Adamawa, ni baálé ilé kan, Ọ̀gbẹ́ni Aliyu Yakubu, ẹni ọdún mẹ́rìndínlọ́gọ́rin kan tó pa ọ̀rẹ́ rẹ̀, Olóògbé Bassey Isah, wà báyìí, ó ń ran wọ́n lọ́wọ́ nínú ìwádìí wọn nípa ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn án.
Oun tá a gbọ́ ni pé se ni afurasí ọdaràn ọhún tó ń gbé lágbègbè Jalingo-Daddawa, nílùú Uba, nijọba ìbílẹ̀ Hong, ni ìpínlẹ̀ Adamawa, dọgbọn gba àpò àgbàdo mẹta lọwọ olóògbé náà pé òun maya bá a ṣoogun owó tó fi máa lówó rẹpẹtẹ. Lẹ́yìn tó fi ẹtan gba àpò àgbàdo mẹta náà tán lọwọ rẹ̀ lọ bá tan olóògbé lọ sínú igbó kékeré kan lọjọ kẹtala, oṣù Kẹfà, ọdún yìí, níbẹ̀ ló sì pa a sí. Lẹyin to pa a tan lo ba sinku rẹ sinu igbo nibẹ. Ṣùgbọ́n àṣírí ohun tó ṣe yìí padà tú síta, àwọn ọlọpaa si lọọ fọwọ òfin mu un ju sahaamọ wọn.
Alukoro ileeṣẹ ọlọ́pàá ìpínlẹ̀ Adamawa to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Ẹti tó kọjá, sọ pe iwa to lodi sofin ipinlẹ naa patapata ni afurasi ọdaran ọhun hu nipa bo ṣe dọgbọn gba apo agbado mẹta lọwọ olóògbé, to si tan an lọ sinu igbo, to si pa a. Lẹyin to tun ṣe gbogbo eleyii tan lo tun ji awọn dukia rẹ kan bii mọto ayọkẹlẹ Toyota Starlet, ọkada ati Kẹkẹ-Marwa rẹ.
Àtẹ̀jáde kan tí wọ́n fi síta lórí ìṣẹ̀lẹ̀ ọhún lọ báyìí pé, ‘’Ọdọ wa ni afurasí ọdaran Yahaya tó ń gbé agbègbè Jalingo-Daddawa wà báyìí, o dọgbọn gba àpò àgbàdo mẹta lọwọ́ Olóògbé Bassey ni, ó lóun máa bá a ṣoogun owó tó fi máa lówó rẹpẹtẹ lọjọ kẹtala, oṣù Kẹfà, ọdún yìí. Ló bá tàn án lọ sínú igbó kan, níbẹ̀ ló ti la olugbongbo mọ́ ọn lórí, lẹ́yìn tí olóògbé náà kú tán ló bá sìnkú rẹ̀ sínú igbó níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àṣírí rẹ̀ padà tú, afurasí ọdaràn ọhún sì ti jẹ́wọ́ fawọn ọlọ́pàá tí wọ́n mú un.
Alukoro ní àwọn máa tó fojú rẹ̀ ba ilé ẹjọ́ lẹyìn tawọn ba parí ìwádìí àwọn nípa rẹ̀.