Wọ́n gbaṣọ lọ́rùn òsìṣẹ́ ológun t’ójalè
Ọrẹ Òtítọ́jù
Àwọn aláṣẹ iléeṣẹ́ ológun oríléèdè Nàíjírìà ti kéde pé àwọn ti gbaṣọ lọ́rùn ṣọ́jà obìnrin kan, Kọ́púrà Jonah Comfort, tí nọmba ìdánimọ̀ rẹ jẹ ‘15NA/74/4422F’.
Ọkan lara iyawo ọga rẹ to n gbe nipinlẹ Kaduna, ni ṣọja naa n ṣọ, ṣugbọn ko fi ọrọ rẹ mọ nibi iṣẹ ti wọn gba a fun naa, niṣe lobinrin ologun yii wọle sinu yara iyawo ọga naa, to si ji goolu olowo nla kan, lẹyin naa lo lọọ ta a ni gbanjo fun Hausa kan laarin ilu naa.
Ninu oṣu Karun-un, ọdun yii, ni ṣọja naa ji goolu iyawo ọga rẹ tiye rẹ jẹ miliọnu marundinlogoji (N35M), ṣugbọn to lọọ ta a ni miliọnu marun-un Naira (5M) pere fun Mọla kan.
Agbọ pe ṣe ni ṣọja ọhun yọ kẹlẹkẹlẹ wọnu yara ọga rẹ lọjọ kan ninu oṣu Karun-un, ọdun yii, to si ji goolu olowo iyebiye ọhun gbe. Lẹyin iwadii tawọn ṣọja naa ṣe ni wọn ri ẹri pe Comfort lo ji goolu iyawo ọga rẹ gbe nibi tiyẹn tọju rẹ si.
Lẹyin to jẹwọ fawọn ọga rẹ pe loootọ loun ji awọn goolu naa ni wọn too ṣe idajọ rẹ, ti wọn si le e danu lẹnu iṣẹ fun iwa palapala to hu ọhun.
Ṣa o, wọn ti lọọ mu Hausa to ra ọja ole naa lọwọ ṣọja yii lowo pọọku.
Bẹ o ba gbagbe, aipẹ yii ni awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orileede yii gbaṣẹ lọwọ awọn ṣọja mẹta kan ti awọn ọlọpaa mu fun ẹsun ole jija, iwa ijinigbe atawọn oniruuru iwa ọdaran laarin ilu.
Inu oṣu Kẹrin, ọdun yii, lawọn ọlọpaa fọwọ ofin mu wọn lasiko ti wọn n ṣiṣẹ ibi wọn lọwọ, lẹyin ti wọn mu wọn tan ni wọn fa wọn le awọn alaṣẹ ileeṣẹ ologun orileede yii lọwọ lati da sẹria fun wọn.
Loju-ẹsẹ ni wọn ti ṣewadii nipa ẹsun ti wọn fi kan wọn, wọn ri i pe loootọ ni wọn jẹbi, wọn si kede pe wọn ti gbaṣẹ lọwọ wọn.