Gómìnà Adeleke ṣelédè lẹ́yìn Murphy Afolabi

Gómìnà Adeleke ṣelédè lẹ́yìn Murphy Afolabi

Fẹ́mi Akínṣọlá

Báa kú làá dère, èèyàn ò sunwọ̀n láàyè.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun, Ademola Adeleke ti bá àwọn ẹbí, ará àti akẹgbẹ́ Murphy Afolabi tó di olóògbé lọ́jọ́ Àìkú kẹ́dùn lórí àdánù ńlá yìí.

Àtẹ̀jáde kan tí agbénusọ gómìnà Adeleke, Mallam Olawale Rasheed fi léde lọ́jọ́ Ajé ní ìlú Osogbo júwe Murphy Afolabi gẹ́gẹ́ bí ẹni tó ṣojú ìpínlẹ̀ Osun dáradára nígbà ayé rẹ̀.

Adeleke ní Afolabi lo ìgbé ayé rẹ̀ láti farajìn sí iṣẹ́ eré tíátà tó gbé dání, tó sì fi hu ìwà ọmọlúàbí títí tó fi jẹ́ Ọlọ́run nípè.
Ó ṣàlàyé pé nígbà tí Afolabi ṣe àbẹ̀wò sí òun kó tọ di wí pé ọlọ́jọ́ dé, ó ní ọ̀rọ̀ àwọn ìpèníjà tó ń bá ẹ̀ka ètò eré ìdárayá ni àwọn jọ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

“A fẹnukò lórí àwọn ètò tó le sọ ìpínlẹ̀ Osun di oríko ilé àṣà àti ibi ìnàjú ní ilẹ̀ Yorùbá nígbà náà.”

“Afolabi jẹ́ òṣèré Yorùbá tó nífẹ̀ẹ́ láti máa gbé àṣà àti ìṣe Yorùbá pẹ̀lú ẹ̀bùn eré tí Ọlọ́run fún-un.”

Ó fi kun pé bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ikú Murphy Afolabi jẹ́ èyí tó bani lọ́kàn jẹ́, àwọn gbà pé ó gbé ìgbé ayé tó ṣe é fi yangàn, tó sì máa ń fi ìpínlẹ̀ Osun síwájú nínú gbogbo nǹkan tó máa ń ṣe nígbà ayé rẹ̀.

“Mo bá àwọn ẹbí, akẹgbẹ́, ọ̀rẹ́ àti àwọn olólùfẹ́ Murphy Afolabi káàkiri àgbàyé kẹ́dùn lórí ìpapòdà rẹ̀.”

Bákan náà ló gbàdúrà kí Ọlọ́run fún àwọn ẹbí àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ní ọkàn láti gba àdánù wọn.

Ní ọjọ́ Karùn-ún oṣù Karùn-ún ni Afolabi ṣe ayẹyẹ ọjọ́ ìbí ọdún mọ́kàndínláàdọ́ta kí ọlọ́jọ́ tó dé ní ọjọ́ Àìkú, ọjọ́ Kẹrìnlá oṣù Karun-ún ọdún 2023.

Murphy Afolabi ti kópa nínú ọ̀pọ̀lọpọ̀ eré bí i Ifá Olókun, Omowunmi, Wasila Coded àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here