E̩ máa gbé àsà láruge, Òsèré tíátà Lalude ro̩ àwo̩n òǹkò̩tàn Yorùbá

E̩ máa gbé àsà láruge, Òsèré tíátà Lalude ro̩ àwo̩n òǹkò̩tàn Yorùbá

Mary Fágbohùn

Osere tiata, Fatai Oodua, ti a mo si Lalude, ti ro awon onkotan Yoruba lati fi ebun atinuda won han pelu itan won.

Osere naa, eni to soro nibi ayeye kan lati se ayajo ojo ede abinibi olodoodun (Annual Mother Language Celebration Day), ti won se ni gbogan awon odo (BNI Youth Centre), ni fasiti Ibadan, tenumo pataki awon itan Yoruba, o ro awon onkotan lati gbe asa laruge nipa ede naa.

Ayeye naa, ti Atelewo Cultural Initiative sagbekale re ni opin ose, ni won se lati sajoyo ede Yoruba ati asa re.
Nibi ayeye naa ni won tun ti se ifilole itan iseju marun-din-ni-aadota ti oloogbe Pa Gabriel Onibonoje, ogbontarigi onkotan Yoruba, ti won si kede eni to jawe olubori ninu idije eleeketa fun Atelewo ninu itan Yoruba.

Ninu oro re, Lalude nipa akitiyan egbe ibile naa ti won n gbe ede Yoruba laruge nipa ise agbese fun Ogbontarigi iwe ase (‘Ogbontarigi Docuseries Project’) ati ebun Atelewo fun itan Yoruba. O tun ki awon to bori ninu idije naa ku oriire, o si ro won lati tesiwaju lati maa to ipa iperegede naa siwaju si i.

O wi pe, “Mo fe ro gbogbo awon onkowe Yoruba lati fi ebun atinuda won han sii ninu ohun ti won n ko. Bi ise atinuda ba se po to ninu ede Yoruba, bee ni yoo se maa mu ki didara itan Yoruba goke si ni Nollywood. Nitori naa, e je ka tesiwaju lati maa so awon itan ti o mu ewa asa Yoruba jade ki a si je ki ebun atinuda gbori ninu bi a n se n ko itan.”

Awon to jawe olubori ninu idije itan naa ni won kede nibi ayeye naa. Mr. Babatunde Shittu ni won kede pe o jawe olubori ni gbogbo re pata fun itan re to ko “Láàdì” ti o si gba ebun owo ọ̀kẹ́ méjìlá àbọ̀ naira.
Jimoh Aderoju ni won yan fun ise afowoko re ‘Àròfọ̀ Àsìkò; Alimi Omosalewa fun aayan ogbufo si ede Yoruba to se fun itan ‘Women of Owu’ lati owo Prof. Femi Osofisan si ‘Awon Obinrin Owu,’ ati Rasheed Adeniyi fun iwe afowoko re ti o pe akole re ni ‘Nǹkán Yan.’ Gbogbo won si gba ebun owo oke marun naira ni eni kookan.

Lalude soro lori pataki sise itoju ati gbigbe ede ati asa Yoruba laruge nipa itan. O wi pe awon onkotan Yoruba ni won ni ojuse lati ri pe ede ati asa naa n tesiwaju lati ma a gbeeru, o si pe won lati fi ebun atinuda won ati ogbon won han ninu ohun ti won n ko.
Ifilole itan nipa igbesi aye oloogbe Pa Onibonoje je ohun miiran to laami nibi ayeye naa. Itan iseju marun-din-ni-aadota naa so nipa bi won se bii, ibere aye re, bi o se bere ise gbigbe iwe jade, awon ipenija re, awon aseyori re, ati ilowosi re ninu agbejade omo onile titi de igba to feyinti lenu okowo re.

LEAVE A REPLY

Please enter your comment!
Please enter your name here