Home ÀKỌ̀TUN Igboho padà sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nilùú Ibadan
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 3 days ago

Igboho padà sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nilùú Ibadan

Igboho padà sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn nilùú Ibadan

Ọrẹ Òtítọ́jù

Kò jọ pé lọbọlọbọ aáwọ̀ láàrin Olóyè Sunday Adeyẹmọ àti Ìjọba àpapọ̀ tíì jẹrodò munmi o.
Ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ àwọn olólùfẹ́ gbajúmọ̀ ajàfún ìdásílẹ̀ orílẹ̀ Yorùbá n nì, Olóyè Sunday Adeyẹmọ tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Sunday Igboho ló kún ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn tó wà nílùú Ìbàdàn l’Ọ́jọ́rú.

Ni ile ẹjọ kotẹmilọrun to wa nilu Ibadan ni igbẹjọ ti n waye lori ẹjọ kotẹmilọrun ti ijọba apapọ pe tako Sunday Adeyẹmọ ti ọpọ eeyan mọ si “Sunday Igboho”.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Sunday Igboho wọ ijọba apapọ orilẹede Naijiria lọ si ile ẹjọ giga ipinlẹ Ọyọ niluu Ibadan, nibi ti o ti beere fun ẹẹdẹgbẹta Biliọnu naira, owo gba mabinu fun ile rẹ ti ileeṣẹ ọtẹlumuyẹ orilẹede Naijiria, DSS kọlu lọjọ kinni oṣu keje ọdun 2021.

Ile ẹjọ naa gbe idajọ kalẹ lori ẹjọ ọun nigba naa pe ki ajọ agbofinro DSS o lọ san ogun biliọnu naira fun Sunday Igboho.

Ijọba apapọ ko tẹwọgba idajọ ile ẹjọ to ni ki wọn san ogun Biliọnu naira fun Sunday Igboho, eyii lo si ṣokunfa bi ẹjọ naa ṣe de ile ẹjọ kotẹmilọrun.

Aago meji ọsan Ọjọru ni igbẹjọ naa bẹrẹ, ṣugbọn awọn alatilẹyin Sunday ti o fara han nile ẹjọ ko ni anfani lati wọle sinu gbọngan igbẹjọ ni ile ẹjọ naa.

Awọn agbofinro to duro lẹnu ọna ṣe alaye wi pe eeyan perete nikan ni yoo lanfani lati de ibi igbẹjọ naa.

Bakan naa ni awọn akọroyin ko ni anfani lati wọle si ibi igbẹjọ naa.

Agbejọro fun Sunday Igboho, Amofin Yọmi Aliyu wa nibi igbẹjọ naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…