Olùdíje ẹgbẹ́ APC fẹ̀yìn alátakò rẹ̀ nínú PDP àti SDP janlẹ̀ nínú ìbò gómìnà Ekiti
Olùdíje ẹgbẹ́ APC fẹ̀yìn alátakò rẹ̀ nínú PDP àti SDP janlẹ̀ nínú ìbò gómìnà Ekiti
Fẹ́mi Akínṣọlá
Àwọn àgbà bọ̀,wọ́n ní o kò sí níbẹ̀, o ní báwo ni wọ́n ṣe pín-in, èyí ló mú kí àwọn aṣojú ẹgbẹ́ òṣèlú kọ̀ọ̀kan ó lajú sílẹ̀ kedere ní ibùdó àjọ elétò ìdìbò INEC tó wà ní ìpínlẹ̀ Èkìtì níbi tí wọ́n ti ka gbogbo èsì ìdìbò ìjọba ìbílẹ̀ kọ̀ọ̀kan.
Òru mọ́júmọ́ òní ni wọ́n parí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí wọ́n se kó àwọn èsì ìdìbò ọ̀hún jọ tán ni Ọ̀jọ̀gbọ́n Fásitì tí àjọ INEC gbà láti wá ṣe alámójútó àgbà níbi ìdìbò ọ̀hún, Ọ̀jọ̀gbọ́n Kayode Adebowale kéde ẹni tó jáwé olúborí.
Iye apapọ ibo ti APC ni ni: 187,057
Ẹgbẹ oṣelu PDP ni apapọ ibo: 67,457
Nigba ti ẹgbẹ oṣelu SDP ni ibo: 82,211
Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò
Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…