Home ÀKỌ̀TUN Kí ipò Ààrẹ lè já mọ́ Yorùbá lọ́wọ́ ni mo ṣejuwọ́ sílẹ̀—Sẹ́nétọ̀ Amosun
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 1 week ago

Kí ipò Ààrẹ lè já mọ́ Yorùbá lọ́wọ́ ni mo ṣejuwọ́ sílẹ̀—Sẹ́nétọ̀ Amosun

Kí ipò Ààrẹ lè já mọ́ Yorùbá lọ́wọ́ ni mo ṣejuwọ́ sílẹ̀—Sẹ́nétọ̀ Amosun

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní kó mọ́ bàjẹ́,kó mọ́ bàjẹ́ laájò àgbà.
Gómìnà ìpínlẹ̀ Ògùn tẹ́lẹ̀, Sẹ́nétọ̀ Ibikunle Amosun ti sọ pé fún àǹfàní kí ipò Ààrẹ lè wá sí ilẹ̀ ẹ Yorùbá lòun ṣe juwọ́ sílẹ̀ lásìkò ètò ìdìbò abẹ́lé tó kọjá yìí.
O sọrọ naa lasiko to n ba awọn alatilẹyin rẹ ti wọn waa ki i ku abọ lati ilu Abuja to ti lọọ dije nibi ibo abẹle funpo aarẹ ẹgbẹ naa APC, eyi to waye ni Gbọngan Alake, to wa ni Abẹokuta l’Ọjọbọ ọsẹ yii.
Gomina tẹlẹ naa ni atilẹyin ti awọn gomina ilẹ Hausa ṣe fun awọn oludije lati apa Guusu lo fa a ti oun fi juwọ silẹ fun Aṣiwaju Bọla Tinubu lasiko idibo abẹle naa.
O ṣalaye pe oun ko ka a si dandan lati di aṣoju ti ẹgbẹ yoo fa kalẹ lasiko idibo abẹle naa. O ni ida ogun ninu ọgọrun ni ifẹ ọkan oun lati di oludije fun ẹgbẹ naa, nigba ti ida ọgọrin ọkan oun wa fun ifẹ ilẹ Yoruba ati orileede Naijiria.
O ni oun ti awọn wo ti igbesẹ naa fi waye pẹlu awọn oludije lati ilẹ Yoruba ni pe bi awọn ba fẹ ki ipo aarẹ wa si ilẹ Yoruba, awọn gbọdọ fi imọ ṣọkan, ki awọn si gbagbe erongba ọkan ẹnikọọkan fun anfaani awọn eeyan agbegbe iha Guusu, paapaa ju lọ, ilẹ Yoruba.
O ni yatọ si Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, ko si ẹnikẹni, boya o ti ku tabi o wa laaye, to sin ipinlẹ Ogun bii toun.
O waa rọ awọn alatilẹyin rẹ pe gbogbo ifẹ, atilẹyin ati adura ti wọn n ṣe fun oun, ki wọn tubọ tẹsiwaju, ṣugbọn ki wọn nawọ rẹ si ẹni ti ẹgbẹ fa kalẹ lati dije dupo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu APC, ki wọn si ṣe atilẹyin fun un ko le rọwọ mu lasiko ibo ọdun to n bọ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…