Home ÀKỌ̀TUN Ìdìbò ọdún 2023, Atiku kéde Ifeanyi Okowa bí igbákejì rẹ̀
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 1 week ago

Ìdìbò ọdún 2023, Atiku kéde Ifeanyi Okowa bí igbákejì rẹ̀

Ìdìbò ọdún 2023, Atiku kéde Ifeanyi Okowa bí igbákejì rẹ̀

Ọrẹ Òtítọ́jù

Olùdíje sípò Ààrẹ Orílẹ̀ yìí nínú ẹgbẹ́ òṣèlú PDP, Atiku Abubakar, ti kéde gómìnà ìpínlẹ̀ ẹ Delta, Ifeanyi Okowa, gẹ́gẹ́ bí i igbákejì i rẹ̀.

Atiku funra rẹ lo kede orukọ Okowa nibi eto kan ti wọn ṣe niluu Abuja, ko to fi ikede naa sita loju opo Twitter rẹ.

Nigba to n sọrọ lori eredi to ṣe yan Okowa, Atiku sọ pe ẹni ti yoo ṣe igbakeji oun gbọdọ jẹ ẹni ti yoo le di ipo Aarẹ mu, ti yoo si le ṣe atilẹyin fun oun gẹgẹ bii Aarẹ.

O fi kun pe irufẹ ẹni bẹẹ gbọdọ ṣe afihan iṣokan Naijiria ati ẹni ti ko ni bẹru lati sọrọ soke ti nnkan ko ba lọ dede, ti yoo si le fun ijọba ni amọran to dara.

Atiku tun sọ pe igbakeji oun gbọdọ ni imọ nipa ibi ti nnkan bajẹ de ni Naijiria ati ọna ti awọn fi le ṣe atunṣe.

Ohun to kan lẹyin ikede yii
Ni bayii ti wọn ti kede Okowa gẹgẹ bii ẹni ti yoo dije bii igbakeji Atiku, igbimọ kan yoo ṣe ayẹwo ati iwadii ọkunrin naa.

Ṣaaju lawọn eeyan kan ti kọkọ n sọ pe gomina Nyesom Wike ni Atiku yoo yan gẹgẹ bii igbakeji rẹ.

Amọ lọjọru ni ẹgbẹ oṣelu PDP kede pe ko si ohun to jọ pe awọn yoo yan Wike gẹgẹ bii igbakeji Atiku.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…