Home ÀKỌ̀TUN Hèèmọ̀! Ajínigbé jí olórí ìjọ Anglican àtìyàwó ẹ̀ gbé pẹ̀lú awakọ̀ wọn lọ́nà Ògbómọ́ṣọ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

Hèèmọ̀! Ajínigbé jí olórí ìjọ Anglican àtìyàwó ẹ̀ gbé pẹ̀lú awakọ̀ wọn lọ́nà Ògbómọ́ṣọ́

Hèèmọ̀! Ajínigbé jí olórí ìjọ Anglican àtìyàwó ẹ̀ gbé pẹ̀lú awakọ̀ wọn lọ́nà Ògbómọ́ṣọ́

Ọrẹ Òtítọ́jù

Inú-un kọ̀bàkòle ni gbogbo ìjọ Anglican nílẹ̀ yìí wà báyìí, bẹ́ẹ̀ lọkàn ọ̀pọ̀ ọmọnìyàn nílẹ̀ ẹ Yorùbá kò fi ìbàlẹ̀ẹ ọkàn rìnrìn àjò pẹ̀lú u bí àwọn ajínigbé ṣe jí olórí ìjọ náà àtìyàwó ẹ̀ gbé pẹ̀lú awakọ̀ wọn lórí ìrìn-àjò.
Ẹni-ọwọ agba Aderọgba, to jẹ biṣọọbu ijọ Anglican fun gbogbo ẹkun Jẹbba nipinlẹ Kogi, ati iyawo ẹ pẹlu awakọ wọn lawọn ọbayejẹ ẹda kan ti wọn dihamọra pẹlu ibọn ji gbe nigba ti wọn n ti ilu Jẹbba lọ si Yewa, nipinlẹ Ogun.

Bo tilẹ jẹ pe awọn iranṣẹ eṣu ọdaran yii ko ti i pe awọn mọlẹbi Biṣọọbu naa lati sọ nnkan ti wọn n fẹ gan-an lọwọ wọn, iriri gbogbo ọmọ orileede yii lati nnkan bii asiko diẹ sẹyin, fi han pe awọn ajinigbe lo da wọn lọna loju ọna tuntun to so Ogbomọṣọ ati ilu Ọyọ pọ, ti wọn si fi ibọn sin wọn wọnu igbo lọ ni nnkan bii aago mẹsan-an aarọ ọjọ Aiku, ọjọ kejila, oṣu Kẹfa, ọdun 2022 yii, ti wọn si ji wọn gbe.

Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Adewale Ọṣifẹṣọ, ti fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, o ni loju-ẹsẹ ti wọn ti fi iṣẹlẹ yii to awọn leti lawọn agbofinro ti bẹrẹ iwadii lati ri awọn eeyan Ọlọrun naa tu silẹ nigbekun awọn ajinigbe.
O ni, “Iwadii fi ye wa pe lasiko ti ọkọ awọn Biṣọọbu yẹn bajẹ loju ọna lawọn afurasi ajinigbe naa yọ si wọn lojiji, ti wọn si ji wọn gbe.

“Igbakeji ọga agba ọlọpaa ipinlẹ yii to jẹ alamoojuto iṣẹ agbofinro lo ko ọpọlọpọ igbimọ oluwadii lẹnu iṣẹ ọlọpaa lẹyin lati le ri awọn eeyan naa gba silẹ laaye ati lai fara pa.

“Lara awọn ikọ to n sa gbogbo agbara wọn lati wa awọn eeyan naa kan, ki wọn si gba wọn silẹ, ni ikọ awọn agbofinro to n gbogun ti ijinigbe, ikọ ayọkẹlẹpẹkun, awọn adigboluja, awọn to n koju iṣẹlẹ igbesunmọni ati bẹẹ bẹẹ lọ.’’

O waa fi ọkan awọn araalu balẹ lati maa ba iṣẹ oojọ wọn lọ lai foya, o ni awọn agbofinro ti gbakoso eto aabo layiika wọn gbogbo.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…