Home ÀKỌ̀TUN ASUU” ní àwọn kò bèèrè ẹ̀dáwó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni láti wọlé padà
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

ASUU” ní àwọn kò bèèrè ẹ̀dáwó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni láti wọlé padà

“ASUU” ní àwọn kò bèèrè ẹ̀dáwó lọ́wọ́ ẹnikẹ́ni láti wọlé padà

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ṣé wọ́n ní sà-án là á rìn,ajé ní-ín múni sẹ́kọ́nà rìn. Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ Fásitì nílẹ̀ yìí ti ní àwọn ti kọ owó tí àwọn èèyàn kójọ kí wọ́n lè padà sí iléẹ̀kọ lójú ọjọ́.

Àwọn olùkọ́ Fásitì ọ̀hún ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ wíwoṣẹníran nínú Oṣù Kejì látàrí pé Ìjọba àpapọ̀ kọtí ọ̀gbọin sí sísanwó osù àti owó àjẹmọ́nú un wọn.

Lẹyin ti ẹgbẹ ASUU kede pe iyanṣẹlodi naa yoo tẹsiwaju da Oṣu Kẹjọ ni ileeṣẹ Redio Berekete Family Radio wa bẹrẹ si ni beere owo lọwọ awọn ara ilu fun ajọ naa.

Ni Ọjọ Satide ohun ni ileeṣẹ redio naa, Ọjọgbọn Emmanuel Osodeke pe aarẹ ẹgbẹ naa wa si ori eto .

Bi wọn ṣe n ṣe eto naa lọ ni atọkun ti wọn n pe ni ‘Ordinary President’ bẹrẹ si ni da owo silẹ, to si sọ pe gomina kan fun wọn ni aadọta miliọnu naira ti awọn si fẹ ko biliọnu mejidinlogun naira jọ fun wọn.

Amọ aarẹ naa gba ẹrọ agbohunsafẹfẹ to si sọ pe awọn ko fẹ owo naa, ki ẹnikẹni ma si da ASUU mọ irufẹ owo bẹẹ.

O ni idi ti awọn fi wa si ori eto naa ni lati kede idi ti awọn fi gunle iyanṣẹlodi.

‘’A ko beere owo lọwọ ijọba apapọ fun ara wa amọ fun awọn fasiti wa kaakiri Naijiria.’’

Lẹyin naa ni ileeṣẹ redio naa kesi awọn eniyan lati fi ‘account number’ wọn ranṣẹ ki wọn le da owo wọn pada.

Amọ awọn to pe si ori eto ni ọjọ naa koro oju si ASUU ati igbeṣẹ wọn naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…