Home ÀKỌ̀TUN Ojọ́ kejìlá, oṣù kẹfà, ọdún 1993 jẹ́ ọjọ́ tí kò ṣe é gbàgbé bọ̀rọ̀ nínú ìṣélú Orílẹ̀ yìí- Ààrẹ Muhammadu Buhari
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

Ojọ́ kejìlá, oṣù kẹfà, ọdún 1993 jẹ́ ọjọ́ tí kò ṣe é gbàgbé bọ̀rọ̀ nínú ìṣélú Orílẹ̀ yìí- Ààrẹ Muhammadu Buhari

Ojọ́ kejìlá, oṣù kẹfà, ọdún 1993 jẹ́ ọjọ́ tí kò ṣe é gbàgbé bọ̀rọ̀ nínú ìṣélú Orílẹ̀ yìí- Ààrẹ Muhammadu Buhari

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ọjọ́ yìí ni àwọn èèyàn Nàìjíríà fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí i Omolúwàbí tòótọ́ tó jáde síta lọ̀ ọ́ dìbò láìsí wàhálà

Ààrẹ Muhammadu Buhari tó ń tukọ̀ Nàìjíríà lọ́wọ́lọ́wọ́ sàlàyé pé irú ọjọ́ yìí kò wọ́pọ̀.

O so eyi lasiko to n ba awọn olugbe Naijiria sọrọ loni ayajọ ọjọ iṣelu awaarawa to jẹ eyi to maa se gbẹyin gẹgẹ bii aarẹ Naijiria.

Aarẹ bu enu ẹ̀tẹ lu awon to wa ni ijoba lasiko naa, eyi ti Ogagun Ibrahim Babangida n dari lori bi wọn se wogile abajade eto idibo naa lodun 1993.

Buhari ni pe eyi safihan ọna idari ti ko dara rara ninu eto oselu Naijiria.
Aare Muhammadu Buhari ni pe pelu ibanuje ni oun n wa nigbagbogbo lori eto aabo Naijiria paapaa awon ajinigbe to n sose nigba gbogbo yii.

O ni oun yoo sapa oun lati rii pe eto idibo odun 2023 lọ ni irọwọrọsẹ laisi itajẹsile.

Ati pe ojutaye ni wọn yoo se gbogbo igbese naa laifi nkankan pamọ fun ara ilu.

Aare Buhari tun sọ nipa ohun to sokunfa yaajo oni ti ọpọ n pe ni June 12.

O sọ ipa ti oloogbe MKO Abiola ko ninu idibo 1993 naa.

Moshood Kashimaawo Olawale Abiola lo bori ninu idije sipo aare Naijiria lodun naa ki ijoba to wa lori aleefa to wọgilee.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…