Home ÀKỌ̀TUN Mínísítà UK ń bá mínísítà Ukraine sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọmọ ilẹ̀ Britain méjì tí Russia dájọ́ ikú fún
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

Mínísítà UK ń bá mínísítà Ukraine sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọmọ ilẹ̀ Britain méjì tí Russia dájọ́ ikú fún

Mínísítà UK ń bá mínísítà Ukraine sọ̀rọ̀ lórí àwọn ọmọ ilẹ̀ Britain méjì tí Russia dájọ́ ikú fún

Fẹ́mi Akínṣọlá

Minisita ọrọ ilẹ̀ okere fun ilẹ̀ United Kingdom, Liz Truss ti ba akẹgbẹ rẹ ti Ukraine, Dmyto Kuleba sọ̀rọ̀ lori idajọ iku ti orílẹ̀èdè Ukraine da fun ọmọ ilẹ̀ Britain meji kan, Aiden Aslin ati Shaun Pinner, pẹlu ọmọ ilẹ̀ Morocco kan, Brahim Saaudun.

Awọn mẹta yii jẹ Sójà ti ikọ̀ ologun Russia mu nígbà ti wọn jagun fun orileede Ukraine.

Ile ẹjọ́ kan to n satilẹyin fun Russia amọ tí kò fi bẹẹ jẹ ìlúmọọkà lagbaye lo dajọ wọn.

Wọn n pe ile ẹjọ́ naa ni “Donetsk People’s Republic”.

Ẹwẹ, Minisita ti UK, Truss tí fi atẹjade si ojú opo Twitter rẹ pe idajọ ti wọn da fun awọn ọmọ ogun yii tapa si ofin ìpàdé àpapọ̀ “Geneva convention” ó sì ní òun àti akẹgbẹ́ òun ti n sọ̀rọ̀ lọ́rori rẹ láti tu wọn silẹ.

Bákan náà, Olóòtúu ijọba UK, Boris Johnson náà ti ní ìyàlẹ́nu ni ìdájọ́ yìí jẹ fun oun to si ti ni ki awọn Mínísítàa méjèèjì ṣe ohun gbogbo ni ikawọ wọn lati rii daju pe wọn gba itusilẹ.

“A fi gbogbo ọna bù ẹnu atẹ lu iru idajọ iku ti wọn fún àwọn ọkunrin yìí, ko si aridaju kankan lati tẹ oju ẹtọ aabo awọn eeyan wọnyi mọ́lẹ̀ “, Agbenusọ Olóòtú sọ bẹ́ẹ̀.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…