Home ÀKỌ̀TUN Osinbajo ati Amaechi kí Asíwájú Bọ́lá Ahmed kú oríire
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - 2 weeks ago

Osinbajo ati Amaechi kí Asíwájú Bọ́lá Ahmed kú oríire

Osinbajo ati Amaechi kí Asíwájú Bọ́lá Ahmed kú oríire

ỌrẹÒtítọ́jù

Igbákejì Ààrẹ orílẹ̀ yìí Ọ̀jọ̀gbọ́n Yẹmí Osinbajo ati minisita eto igbokegbodo oko ti kí Asíwájú Bọ́lá Ahmed kú oríire leẹ́yìn tó jáwé olúborí gẹ́gẹ́ bí i olùdíje fún ipò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú APC.

Ninu atẹjade ti won fi lede ni won ti kii ku oriire, won si gboriyin fun un pe o di opo oṣelu tiwantiwa mu.

‘A ki Asiwaju Bola Ahmed ku oriire pẹlu bi o ṣe laluyọ gẹgẹ bi ẹni ti yoo ṣoju ẹgbẹ naa ninu idibo sipo Aarẹ ni ọdun to n bọ.

Bakan naa ni won tun ki Aarẹ Muhammadu Buhari ku oriire abajade ipade gbogboogbo ti ẹgbẹ oṣelu APC.

Won ni ọpọlọpọ ọdun ni Tinubu fi jẹ opomulero ninu iṣejọba tiwantiwa, eleyii si mu da yatọ laarin gbogbo awọn oludije.

Won ni ọpọlọpọ ọgbọn ati imọ ti Tinubu ni yoo mu tayọ lọna ati jẹ adari lorilẹede Naijiria.

Won tun wa kesi gbogbo awọn ọmọ ẹgbẹ patapata lati gbaruku ti Tinubu ki wọn le de ebute ayọ ni idido to n bọ.

‘’Gẹgẹ bi ẹni to fẹran ilọsiwaju, a gbọdọ ṣe ara wa ni ọkan, ki ẹgbẹ le ni ilọsiwaju.’’

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…