Home ÀKỌ̀TUN Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 26, 2022

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́

Adédoyin ṣépè fáwọn oníròyìn nílé ẹjọ́

Ọrẹ Òtítọ́jù

Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ fáwọn oníròyìn láàárọ̀ Ọjọ́rùú yìí, nígbà tí Dókítà Rahmon Adedoyin bẹ̀rẹ̀ sí í ṣépè fún wọn pé wọ́n ń ya fọ́tò òun.

Adedoyin lo ni ileetura Hilton to wa niluu Ileefẹ, nibi ti akẹkọọ Fasiti OAU kan, Timothy Adegoke, ku si loṣu Kọkanla, ọdun to kọja.

Adedoyin ati awọn oṣiṣẹ rẹ mẹfa ni wọn n jẹjọ lori ẹsun bii mọkanla ti wọn fi kan wọn.
Loṣu kan sẹyin to yẹ ki awọn olujẹjọ bẹrẹ awijare wọn niwaju Onidaajọ Adepele Ojo ti ile-ẹjọ giga ipinlẹ Ọṣun ni agbẹjọro fun Adedoyin, Barisita Ẹlẹja (SAN), sọ pe ko ni ẹlẹrii kankan lati pe.

Nigba to yẹ ki awọn olujẹjọ yooku bẹrẹ awijare ni ọkan lara wọn, Magdalene, bẹrẹ aisan ninu kootu, lẹyin-ọ-rẹyin ni wọn sun igbẹjọ di oni.

Nnkan bii aago mẹsan-n kọja iṣẹju mẹwaa aarọ Ọjọruu ni wọn ko awọn mejeeje de sinu ọgba ile-ẹjọ, nigba ti wọn si n to wọn lọwọọwọ wọnu kootu ni Adedoyin duro lojiji, o kọju si awọn oniroyin, o ni ‘Afi to ba jẹ pe loootọ ni mo pa Timothy Adegoke ni ẹyin ti ẹ n ya fọto yii ko fi ni i jiya laye’.

Ni bayii, igbẹjọ ti bẹrẹ ni pẹrẹu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…