Home ÀKỌ̀TUN Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 25, 2022

Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé-EFCC

Wọ́n ní Okorocha ketí ikún sí ìpé làwọn fi ṣígun kàá mọ́lé mọ́lé

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àjọ tó ń gbógun ti ìwà ìjẹkújẹ lórílẹ̀ yìí, EFCC ti fi ipá mú gómìnà ìpínlẹ̀ Imo tẹ́lẹ̀, Sẹ́nétọ̀ Rochas Okorocha ní ilé rẹ̀ tó wà nílùú Abuja, olú ìlú ilẹ̀ yìí.

Ajọ naa fipa wọ ile Sẹnetọ Rochas Okorocha lẹyin ti iro ibọn dun lakọlakọ.

Bakan naa ni wọn fipa le awọn akọroyin kuro ni ile Sẹnetọ naa to tun wa lara awọn to n dije fun ipo aarẹ Naijiria labẹ aṣia ẹgbẹ oṣelu APC.

Ninu atẹjade ti ajọ EFCC fi soju opo Ayelujara Facebook rẹ, ajọ naa ni awọn ti n ranṣẹ pe gomina tẹlẹ naa pe ko wa yọju si awọn lẹyin to ti kọkọ sa labẹ beeli ti ajọ naa fun un nigba ti wọn kọkọ mu u, ṣugbọn wọn ni ko dahun.

Ajọ EFCC sọ ọ siwaju ninu atẹjade naa pe igba meji ọtọọtọ lawọn ti gbe ẹjọ naa de iwaju adajọ nilu Abuja ṣugbọn ti wọn ko lee gbọ ẹjọ naa nitori aifarahan Sẹnetọ Rochas Okorocha nile ẹjọ.

O fi kun un pe ọgbọn ọjọ oṣu karun un ni igbẹjọ naa yoo si tun waye pẹlu bi adajọ ti ṣe fi ohun silẹ pe oun ko tun ni gba sisun igbẹjọ naa siwaju mọ lọtẹ yii lo faa ti awọn fi gbe igbesẹ naa.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…