Ènìyàn márùn-ún wà láàyè, mẹ́ta ti kú nínú ilé tó dàwó ní ìpínlẹ̀ Eko— Àjọ LASEMA
Ènìyàn márùn-ún wà láàyè, mẹ́ta ti kú nínú ilé tó dàwó ní ìpínlẹ̀ Eko— Àjọ LASEMA
Fẹ́mi Akínṣọlá
Ògédé ẹni orí bá kó yọ nìkan ló móríbọ́ nínú-un làáṣìgbò àti pákáleke ayé.
Àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì níìpínlẹ̀ Èkó, LASEMA sọ pé èèyàn márùn-ún ni òun ti rí yọ jáde lábẹ àlàpà ilé tó wó ní Lagos Island lọ́jọ́ Sátidé, ọjọ́ kọkànlá, oṣù Karùn-ún, ọdun 2022.
Àtẹ̀jáde tí agbẹnusọ àjọ LASEMA, Ọ̀mọ̀wé Damilola Oke-Ọsanyintolu fi síta ní òwúrọ̀ kùtù ọjọ́ Àìkú, sọ pé wọ́n tún yọ òkú èèyàn mẹ́ta ní abẹ́ ilé ọ̀hún lóru mọ́jú.
Ọ̀mọ̀wé Osanyintolu sọ pé àwọn ti dé àjà tó kẹ́hìn nínú ilé nàá.
Èyí tó túmọ̀ sí pé iṣẹ́ ìdóòlà ti parí.
Ilé nàá tí wọ́n ń kọ́ lọ́wọ́ ní ojúle kẹrin, Alayaki Lane, ní agbègbè Freeman, Lagos Island ló kọ́kọ́ gbẹ̀mí ènìyàn kan lásìkò tó dàwó.
Lásìkò tí òjò ńlá ń rọ̀ lọ́wọ́ ni ilé náà dàwò lulẹ̀ lójijì.
Gẹ́gẹ́ bí àjọ tó ń mójútó ìṣẹ̀lẹ̀ pàjáwìrì ní ìpínlẹ̀ Eko, LASEMA, ṣe kọ́kọ́ ṣọ, iye ènìyàn tó ṣì há sábẹ́ ilé náà kò jẹ́ mímọ̀.
Adarí àjọ LASEMA, Ọ̀mọ́wé Olufemi Oke-Osanyintolu ní ènìyàn méjì ni àwọn kọ́kọ́ rí yọ láàyè , tí iṣẹ́ sì ń lọ lọ́wọ́ láti yọ àwọn mìíràn tó há sábẹ́ ilé náà.
Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò
Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…