Home ÀKỌ̀TUN Agbébọn pa Họ́nọ́rébù Okechukwu Okoye ní ìpínlẹ̀ Anambra ,wọ́n tún gé orí rẹ̀ sọnù
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 22, 2022

Agbébọn pa Họ́nọ́rébù Okechukwu Okoye ní ìpínlẹ̀ Anambra ,wọ́n tún gé orí rẹ̀ sọnù

Agbébọn pa Họ́nọ́rébù Okechukwu Okoye ní ìpínlẹ̀ Anambra ,wọ́n tún gé orí rẹ̀ sọnù

Ọrẹ Òtítọ́jù

Gómìnà ìpínlẹ̀ Anambra, Ọ̀jọ̀gbọ́n Charles Chukwuma Soludo ti bu ẹnu àtẹ́ lu ikú aṣòfin Họ́nọ́rébù Okechukwu Okoye tí ọ̀pọ̀ mọ̀ sí “Okey Di Okay.”

Ó tún ṣèlérí mílíọ̀nù mẹ́wàá Náírà gẹ́gé bí ẹ̀bùn owó fún ẹnikẹ́ni tó bá leè mú ìròyìn tí yóó ran àwọn agbófinró lọ́wọ́ láti ṣàwárí àwọn òbìlẹ̀jẹ̀ ọ̀hún.

“Pẹlu ẹdun ọkan ati ibanujẹ nlanla ni Ọjọgbọn Chukwuma Charles Soludo gbọ iroyin bi wọn ṣe pa Họnọrebu Okechukwu Okoye, aṣofin to n ṣoju ẹkun idibo Aguata II nileegbimọ aṣofin ipinlẹ yii ati amugbalẹgbẹ rẹ Cyril Chiegboka.

“Ni jọ karundinlogun oṣu karun un lawọn apaniyan wọnyii ji Họnọrebu Okoye ati Cyril Chiegboka gbe loju ọna.”

Gomina Soludo ba awọn mọlẹbi aṣofin naa nilu Isuofia kẹdun.

O ni o ṣeeṣe ki awọn to pa Họnọrebu Okoye jẹ ẹgbẹ ọdaran kan naa to kọlu oun lọdun meji sẹyin ti wọn si pa ọlọpaa mẹta.

O ni awọn ọdaran yii ko lee gba ijọba lẹkun Usofia tabi ni ipinlẹ Anambra.

O wa ṣeleri lati mu awọn ọdaran to ṣiṣẹ laabi naa ati gbogbo awọn to n da ipinlẹ naa laamu.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…