Home ÀKỌ̀TUN Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 18, 2022

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Bí ẹgbẹ́ òṣèlú ù mi bá fàmí kalẹ̀, ìyókù sẹ́pẹ́rẹ́—Tinubu

Ọrẹ Òtítọ́jù

Olùdíje fún ipò Ààrẹ lẹ́gbẹ́ òṣèlú All Progressives Congress, APC, àti adarí àpapọ̀ ẹgbẹ́ òṣèlú ọ̀hún, Aṣíwájú Bọla Ahmed Tinubu, ti rọ àwọn alátìlẹ́yìn rẹ̀ àtàwọn aṣojú ẹgbẹ́ náá pé kí wọ́n rọ̀jò ìbò wìtìwìtì f’óun lásìkò ètò ìdìbò abẹ́lé tó ń bọ̀ lọ́nà yìí, torí tóun bá fi lè jáwé olúborí, tí wọ́n sì fa òun kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọmooyè fúnpò ààrẹ, kò sí olùdíje kankan nínú ẹgbẹ́ òṣèlú Peoples Democratic Party, PDP, tó lè bá òun figagbága tó bá dọ̀rọ̀ ìdíje fúnpò Ààrẹ nínú ètò ìdìbò gbogbogbòò lọ́dún 2023.

Tinubu sọrọ yii lasiko to n fikun lukun pẹlu awọn aṣoju ẹgbẹ APC niluu Makurdi, ipinlẹ Benue, lọjọ kẹtadinlogun, oṣu Karun-un yii.
Gomina ipinlẹ Eko tẹlẹ naa, Tinubu, sọ pe “Mo rọ yin pe kẹ ẹ fun mi ni tikẹẹti ẹgbẹ APC tori ko le si ọrọ fifigagbaga laarin emi ati ẹnikẹni ti ẹgbẹ oṣelu alatako, PDP, ba fa kalẹ lọdọ wọn.
“Mo maa lo iriri mi nipo adari ti mo ti wa gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Eko, ati ọna iṣakoso mi ni Naijiria tẹ ẹ ba dibo yan mi sipo aarẹ orileede yii.
“Mo fọwọ sọya pe ijọba ti ma a ṣe, ijọba to maa ṣe kedere si gbogbo eeyan ni, ko ni i si fifi igba kan bọ’kan ninu, gẹgẹ bii aarẹ. Naijiria lọrọ, ohun to kan ku fun wa ni ka dari awọn nnkan amuṣọrọ ati alumọọni wa sọna to tọ, ti yoo ṣe gbogbo wa lanfaani.”
Tinubu tun parọwa sawọn ọdọ pe ki wọn fọkan tan oun, o ni toun ba di aarẹ, gbogbo ireti ati afojusun wọn loun maa ṣiṣẹ le lori, oun o si ni i ja wọn kulẹ.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…