Home ÀKỌ̀TUN Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ
ÀKỌ̀TUN - orisiirisii - Orisirisi - May 17, 2022

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Rògbòdìyàn ẹgbẹ́ onímọ́tò Èkó n fẹ́jú kẹkẹ

Ọrẹ Òtítọ́jù

Àwọn àgbà sọ pé ìjàngbọ̀n kìí nìkan dárìn,bí kò ju bíntín, yóó fọwọ́ kọ́ nǹkan .
Ó ti ń fojú hàn pé rúkèrúdò mí-ìn ti ń kànkù gbọ̀ngbọ̀n báyìí nínú ẹgbẹ́ àwọn awakọ̀, tí amọ̀ sí “NURTW” bí wọ́n ṣe ní kí Olúọmọ filé ẹgbẹ́ àwọn sílẹ̀.

Ẹgbẹ Naṣana, ti wọn tun n pe ni NURTW ti ni ki awọn ẹgbẹ tuntun tijọba ipinlẹ Eko ṣẹṣẹ fi lelẹ, iyẹn ‘Lagos State Parks Management Committee’ , ti Alaaji Musiliu Ayinde Akinsanya ti ọpọlọpọ awọn eeyan mọ si ‘MC Oluọmọ’ jẹ olori fun, palẹ ẹru wọn mọ nile ẹgbẹ ọhun to wa ni Ladoje, agbegbe Agege, nipinlẹ Eko
Alaga igbimọ awọn ti wọn n mojuto nnkan ini ẹgbẹ NURTW nipinlẹ Eko, Fatai Adeṣina ti awọn eeyan ẹ mọ si Akewejẹ sọrọ yii lakooko ti wọn n ṣepade pẹlu awọn oniroyin lopin ọsẹ to kọja yii.
Ta o ba gbagbe, alaga ẹgbẹ NURTW ti ẹka ipinlẹ Eko tẹlẹ, MC Oluọmọ, lo ti kede nita gbangba pe oun ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ NURTW ọhun mọ, eyi waye lẹyin ti awọn igbimọ apapọ ẹgbẹ da a duro fungba diẹ lori ẹsun pe o n tasẹ agẹrẹ si ofin ẹgbẹ, awọn adari ẹgbẹ atawọn ẹsun mi-in.
Lẹyin eyi ni Gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu, yan an gẹgẹ bii alaga ati adari ẹgbẹ onimọto tuntun ti wọn da silẹ niluu Eko, iyẹn ‘Lagos State Parks Management Committee’ lati maa mojuto awọn ọkọ akero nipinlẹ ọhun.
Nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ nipinlẹ Eko, Adeṣina rawọ ẹbẹ si gomina Sanwo-Olu lati pa a laṣẹ fun MC Oluọmọ atawọn eeyan ẹ ki wọn yee lo ile ẹgbẹ NURTW niwọn igba to ti jẹ pe wọn ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ naa mọ.

Ninu ọrọ ẹ lo ti ni, “Ko bojumu, bẹẹ lo ta ko laakaye. O ti kede pe o ki i ṣe ara ẹgbẹ mọ, o tun waa kọ, o o fẹẹ fi awọn nnkan ini ẹgbẹ ọhun silẹ.
“Ẹbẹ la n bẹ ijọba ipinlẹ Eko lati dakun ba wa ba awọn eeyan wọnyi sọrọ ki wọn kuro lọọfiisi wa. NURTW lo nile ẹgbẹ ọhun, niwọnba igba tẹ ẹ si ti sọ pe ẹ ki i ṣe ọmọ ẹgbẹ wa mọ, mo lero pe o yẹ kẹ ẹ ko gbogbo nnkan ẹgbẹ ọhun to ba wa lakata yin silẹ.
“Gbogbo wa ni ọmọ ẹgbẹ pataki ninu ẹgbẹ oṣelu APC, asiko ibo la si ti wa yii, a o fẹ ohunkohun to le da omi alaafia ipinlẹ yii ru, idi niyi ta a fi n rọ Oluọmọ atawọn eeyan ẹ lati jọwọ nnkan ini ẹgbẹ wa silẹ fun wa.
Lara awọn ofin to wa nilẹ ni pe ka gba gbogbo nnkan to jẹ ti ẹgbẹ, titi kan owo to wa lọwọ awọn oloye ijọba ẹgbẹ ọhun tẹlẹ”.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *

Check Also

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò

Àwo̩n aké̩kò̩ó̩ WASCCE tó fi ìsekúse parí ìdánwò Yìnká Àlàbí O ma se o! Awo̩n ake̩ko̩o̩…